Wọn ti sinku Lanre Jimoh, ọga ọlọpaa ipinlẹ Cross River to jẹ ọmọ bibi Ilọrin

Stephen Ajagbe, Ilọrin

Ọjọ Abamẹta, Satide, ni wọn sinku Abdulkadir Lanre Jimọh, ọmọ bibi ilu Ilọrin to jẹ kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Cross River, si ile rẹ to wa ni GRA, niluu Ilọrin.

Ọpọlọpọ awọn olubanikẹdun lo pejọ sagbegbe ti wọn ti sinku naa pẹlu bi awọn ọlọpaa ṣe bu ọla ikẹyin fun un.

Imaamu agba ilu Ilọrin, Dokita  Mohammad Bashir Imam Soliu (OON), lo ṣaaju adura isinku naa ni nnkan bii aago meji kọja, lẹyin naa ni wọn gbe oku ọkunrin naa wọ kaa ilẹ lọ.

Bo tilẹ jẹ pe ko ti i sẹni to mọ pato ohun to pa a, sibẹ, Ọga agba ilewosan ẹkọṣẹ Fasiti ilu Calabar, UCTH, Ikpeme Ikpeme, to kede iku ọkunrin naa lọjọ Ẹti, Furaidee, ni oku ẹ ni wọn gbe de ọsibitu naa laaarọ ọjọ to jade laye.

Ṣugbọn Ikpeme gba awọn to ni ibaṣepọ laipẹ yii pẹlu oloogbe naa nimọran lati lọ fun ayẹwo korona, (Covid-19), ki wọn takete sawọn eeyan, ki wọn si wa nigbele titi ti esi ayẹwo wọn yoo fi jade, ati fun igba diẹ.

Ẹwẹ, ẹgbẹ ọmọ bibi ilu Ilọrin, Ilọrin Emirate Descendants Progressive Union (IEDPU), ti ba ẹbi Elegede to wa ni Ẹruda Quarters, niluu Ilọrin, kẹdun iku ọmọ wọn, Lanre Jimọh.

Aarẹ IEDPU, Alhaji Aliyu Otta Uthman, ninu atẹjade kan sọ pe iku ọlọpaa naa gẹgẹ bii eyi to ba wọn lojiji. O ṣapejuwe oloogbe naa gẹgẹ bii akinkanju ọlọpaa to mu iyi ba ilu rẹ ni gbogbo asiko to fi wa laye.

Leave a Reply