Wọn ti sun igbẹjọ Baba Ijẹṣa sipari oṣu kẹsan-an

Faith Adebọla, Eko

Ẹjọ ifipa bọmọde lo pọ tijọba Eko n ṣe gbajugbaja adẹrin-in poṣonu ilẹ wa nni, Omiyinka James Ọlanrewaju, tawọn eeyan mọ si Baba Ijẹṣa ko le waye l’Ọjọruu, Wẹsidee yii, ti wọn ti ṣeto rẹ si tẹlẹ, niṣe ni wọn sun ẹjọ naa si ipari oṣu to n bọ.

Akọwe kootu to n gbọ ẹjọ akanṣe atawọn ẹsun to jẹ mọ ibalopọ, eyi to fikalẹ siluu Ikẹja, nipinlẹ Eko, nibi ti wọn ti n gbọ ẹjọ naa, kede fawọn agbẹjọro lọtun-un losi atawọn oniroyin pe Adajọ Oluwatoyin Taiwo to n bojuto ẹjọ naa ko si nile, wọn lo lọ fun idalẹkọọ pataki kan ti wọn n ṣe lọwọ fawọn adajọ nipinlẹ Eko.

Akọwe naa ni ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹsan-an, ni igbẹjọ to kan yoo waye, ati pe awọn ti fi iyipada yii to gbogbo awọn ti ẹjọ naa kan leti.

Tẹ o ba gbagbe, lati ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹfa, ni Baba Ijẹṣa ti n jẹjọ lori ẹsun mẹfa ọtọọtọ ti wọn fi kan an, pe o fipa ba akẹkọọ-binrin ọmọ ọdun mẹrinla kan laṣepọ nile oṣere tiata ẹlẹgbẹ rẹ kan, Damilọla Adekọya, ti inagijẹ ẹ n jẹ Princess.

Abilekọ Ọlayinka Adeyẹmi to jẹ agbefọba ijọba ipinlẹ Eko ti mu ẹlẹrii meji wa, awọn agbẹjọro si ti wadii ọrọ wo lẹnu wọn, bakan naa ni ọmọbinrin tọrọ kan ati iya rẹ ti yọju sile-ẹjọ naa, wọn si ti sọ tẹnu wọn.

Ireti wa pe Baba Ijẹṣa lọrọ kan lati ṣalaye bi gbogbo ẹ ṣe jẹ.

Oṣu kẹrin, ọdun yii, lawọn agbofinro lọọ mu Baba Ijẹṣa sahaamọ lori ẹsun ọhun, ahamọ naa lo si wa titi di oṣu kẹfa, tile-ẹjọ fun un ni beeli, lati maa gba ile rẹ waa jẹjọ.

Leave a Reply