Faith Adebọla
Lẹyin ọpọlọpọ ariwo ati ihalẹ awọn ẹgbẹ akẹkọọ pe awọn yoo daṣẹ silẹ ti wọn ko ba yọnda akẹkọọ kan, Aminu Mohammed, ti wọn ti mọ ọgba ẹwọn nitori to kọ ọrọ nipa bi iyawo Buhari, Aishat, ṣe sanra, wọn ti tu ọmọkunrin naa silẹ.
ALAROYE gbọ pe iyawo Aarẹ ti fa iwe ẹjọ to pe e ya, o ni oun ko ba ọmọkunrin naa sẹjọ mọ.
Lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keji, oṣu Kejila yii, ni wọn tu ọmọkunrin to wa ni ipele to gbẹyin nileewe giga Fasiti ijọba to wa ni Dutse, nipinlẹ Jigawa, naa silẹ pe ko maa lọ lalaafia.
Tẹ o ba gbagbe, ni nnkan bii aago mejila ọsan ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Kọkanla, ọdun 2022, ni awọn ọtẹlẹmuyẹ (DSS), lọọ gbe ọmọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogun naa ninu ọgba ileewe wọn. Wọn ni wọn kọkọ fi lulu da batani si i lara, lẹyin naa ni wọn fi panpẹ ofin gbe e lọ si itimọle.
Lẹyin eyi ni wọn foju rẹ bale-ẹjọ, ti Adajọ Halilu Yusuf tile-ẹjọ giga apapọ kan l’Abuja si paṣẹ pe ki wọn ṣi tọju afurasi naa sahaamọ ọgba ẹwọn to wa ni Suleja, nipinlẹ Niger.
Ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lo bu ẹnu atẹ lu igbesẹ naa, ti wọn ni aṣilo agbara ni bi awọn ọtẹlẹmuyẹ ṣe lọọ gbe Mohammed nitori ọrọ to kọ sabẹ fọto iyawo Buhari pẹlu bi obinrin naa ṣe sanra, pe “iya ti tobi si i pẹlu owo awọn araalu to n jẹ”. Eyi lo mu ki awọn akẹkọọ pinnu lati daṣẹ silẹ lọjọ Aje, Mọnde, to n bọ yii. Wọn ni awọn ti bẹ iyawo Aarẹ naa, gbogbo ọna ti awọn si mọ lati gba ki alaafia le jọba lawọn ti ṣe, ṣugbọn ti obinrin naa ko gba. Pẹlu bi Aisha Buhari ṣe fa iwe ẹjọ naa ya bayii, gbogbo ọrọ naa ti rodo lọọ mumi.