Faith Adebọla
Orukọ Aarẹ orileede Amẹrika, Donald Trump, yoo wọnu iwe itan bii Aarẹ ilẹ naa tawọn aṣofin yoo yọ nipo lẹẹmeji leralera, pẹlu bi ile-igbimọ aṣoju-ṣofin wọn ṣe fibo yọ ọ nipo aarẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
Ẹsun ti wọn ka si i lẹsẹ lọtẹ yii ni pe o fi ọrọ ẹnu ẹ runa si rukerudo ati iwọde to waye lọsẹ to kọja yii, ninu eyi ti awọn ọmọlẹyin ẹ kan lọọ ṣakọlu sile-igbimọ aṣofin wọn. Eeyan mẹrin la gbọ pe o doloogbe ninu yanpọnyanrin ọhun.
Bo tilẹ jẹ pe o ku ọjọ meje pere ti Donald Trump yoo fa akoso ijọba le Joe Biden ti wọn kede pe o jawe olubori ninu eto idibo to waye loṣu kọkanla, ọdun to kọja, lorileede ọhun lọwọ, ọgọọrọ awọn araalu Amẹrika lo ti bẹnu atẹ lu bi Trump ṣe fariga lẹyin idibo ọhun, to si n sọrọ ṣakaṣaka, leyii to fa rukerudo to waye, ti wọn tori rẹ yọ ọ nipo lẹẹkeji yii.
Awọn aṣofin okoolerugba o din mẹta lo ti fọwọ si iyọnipo Trump latinu ẹgbẹ oṣelu alatako, Democrats, awọn mẹwaa latinu ẹgbẹ oṣelu Republicans ti Aarẹ naa ti wa lo darapọ mọ wọn, ti iyọnipo naa fi ṣee ṣe.
Amọ ṣa o, ileegbimọ aṣofin agba yoo ni lati jiroro, ki wọn si fọwọ si iyọnipo naa ko too le di mimuṣẹ.
Tẹ o ba gbagbe, iyọnipo bii eyi ti waye lọdun 2019, bo tilẹ jẹ pe ori ko Aarẹ naa yọ nileegbimọ aṣofin agba, pẹlu ẹyọ ibo marun-un pere.