Ija awọn ẹlẹgbẹ okunkun burẹkẹ n’Ikorodu, eeyan mẹrinla lo ti ku

Janjan bii ajere ni ilu Ikorodu ati agbegbe rẹ n gbona lasiko yii, latari bawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ṣe kọju ija sira wọn, ti wọn n dana ibọn ya fun ara wọn, eeyan mẹrindinlogun la gbọ pe o ti ba iṣẹlẹ ọhun rin bayii.

ALAROYE gbọ pe lati bii ọjọ mẹta sẹyin, iyẹn ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii ni ija naa naa ti bẹrẹ lakọtun, to si n fojoojumọ le si i, ẹgbẹ okunkun Aiye ati Ẹiyẹ ni wọn doju ija kọ ara wọn.

Wọn ni awọn adugbo bii Ọbun-Alẹ, Irese, Ladega, Kọkọrọ-Abu, ati Adamọ lawọn afurasi ọdaran naa ti sọ di oju ogun, inu ibẹrubojo si lawọn araalu lawọn adugbo yii wa.

 

Araalu kan, Ọgbẹni Ṣakiru, to n gbe lagbegbe ọhun sọ fakọroyin wa lori aago pe ọrọ naa buru debii pe nnkan bii aago mẹwaa aarọ lawọn eeyan too n ṣilẹkun ṣọọbu ọja wọn, to ba si fi maa di aago mẹrin, ọpọ ni yoo ti maa sare tilẹkun ọja wọn tori lojiji lawọn eeyan n gburoo ibọn kẹu kẹu.

O ni lọpọ igba, lawọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun naa n le ara wọn kiri adugbo pẹlu nnkan ija bii ibọn, ada, ọbẹ aake lọwọ wọn, abalọ ababọ kita kita wọn, wọn yoo ti paayan, awọn mi-in yoo si ti fara gbọgbẹ loriṣiiriṣii.

Ẹlomi-in ti ko fẹ ka darukọ oun sọ pe ki i ṣe kikida awọn ẹlẹgbẹ okunkun ara wọn ni wọn n pa, o loun mọ awọn meji to ti ku ninu wahala nipa aṣita ibọn, tabi ki wọn mọ-ọn-mọ yinbọn pa wọn ni.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Olumuyiwa Adejọbi, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O lọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ mẹrin lara awọn ẹlẹgbẹ okunkun ọhun, wọn si ti wa lahaamọ awọn ọtẹlẹmuyẹ fun iwadii.

Adejọbi ni awọn ti tubọ taari awọn agbofinro tuntun sagbegbe wọnyi, ati pe awọn ọtẹlẹmuyẹ ti wa ni sẹpẹ lati ṣofintoto ohun to n ṣẹlẹ gan-an.

Leave a Reply