Faith Adebọla, Eko
Awọn kansẹlọ ijọba ibilẹ Onidagbasoke Onigbogbo, nipinlẹ Eko, ti fọwọ osi juwe ile fun alaga wọn, Ọnarebu Ọladọtun Ọlakanle, wọn leyi ti baba naa ko jẹ ninu owo kansu ọhun to gẹẹ.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, nibi ijokoo awọn aṣofin kansu naa to waye nirọlẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni Sẹkiteria Onigbongbo, ni iyọnipo naa ti waye.
Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN), sọ pe awọn kansẹlọ mẹfa lo jokoo lori ọrọ ọhun, Kansẹlọ Kayọde Ọpayẹmi lo dabaa pe ki wọn fọwọ si iyọnipo alaga ọhun, ti Kansẹlọ Adebayọ Daudu si keji aba naa.
Nigba ti wọn ni ki wọn dibo lati yọ alaga, awọn kansẹlọ mẹrin lo fọwọ si i pe ki Ọlakunle kuro nipo, ko gba ile ẹ lọ, nigba tawọn meji lawọn o fara mọ ọn, eyi lo mu ki wọn lu u lontẹ pe awọn yọ alaga naa nipo loju ẹsẹ.
Lara ẹsun ti wọn ka si Ọnarebu Ọlakunle lẹsẹ ni pe niṣe lo maa n purọ gba owo lọdọ ijọba, awọn iṣẹ ode ati iṣẹ idagbasoke ti ko ṣẹlẹ lo maa n sọ pe oun ṣe, to si maa lọọ gba owo lọwọ ijọba ipinlẹ.
Wọn ni igba mẹta ọtọọtọ lawọn kansẹlọ ọhun ti kọwe pe e pe ko waa ṣalaye bawọn owo kan to loun ti na sori awọn iṣẹ ode tawọn ko gboorun ẹ ri nijọba ibilẹ naa ṣe jẹ, ṣugbọn niṣe lalaga naa fi wọn gun lagidi, ko yọju si wọn, bẹẹ ni ko ran aṣoju kankan.
Wọn tun fẹsun kan an pe o n nawo ijọba ibilẹ ọhun bulabula, to n ṣe bii ọmọ ọlọdun kiri adugbo, ko si bọwọ fun ofin ilẹ wa to sọ pe o yẹ ko gba iyọnda awọn kansẹlọ ko too tọwọ bọ asunwọn ikowosi kansu ọhun.
Wọn lẹṣẹ ti alaga naa da ta ko akọsilẹ karun-un, ati ikẹjọ, apa ki-in-ni ati akọọlẹ kejilelogun isọri ki-in-ni iwe ofin lori idasilẹ ati eto ijọba ibilẹ nipinlẹ Eko, ti ọdun 2015, eyi ni wọn si ṣe yọ ọ.
Awọn aṣofin naa ti paṣẹ pe ki igbakeji ẹ bẹrẹ iṣẹ lẹyẹ-o-sọka, awọn si ti kọwe si abẹnugan ileegbimọ aṣofin Eko, Mudashiru Ọbasa, lati fi iyọnipo yii to awọn aṣofin ipinlẹ naa leti.
CAPTION: Alaga kansu ti wọn yọ