Wọn tu TOP ka l’Ọṣun, ni gbogbo wọn ba pada sinu ẹgbẹ APC

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Awọn igun ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun ti wọn n pe ni The Ọṣun Progressives (TOP) ti kede titu ẹgbẹ naa ka bayii.

TOP ni wọn da silẹ lasiko ti wahala aarin gomina ana, Alhaji Adegboyega Oyetọla ati ẹni to gbesẹ fun un, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹsọla, le koko, ti awọn mejeeji si pinya.

Nigba naa lọhun-un, awọn ti wọn wa pẹlu Arẹgbẹṣọla bẹrẹ The Ọṣun Progressives, nigba ti awọn ti Oyetọla n pe ara wọn ni IleriOluwa.

Wahala wọn yii lawọn araalu gbagbọ pe o wa lara awọn nnkan to ṣakoba fun ẹgbẹ oṣelu APC ninu idibo gomina oṣu Keje ti wọn fi lulẹ nitori pe ile wọn ko si loju kan naa.

Ṣugbọn ninu ipade oniroyin ti awọn TOP pe lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, abẹnugan ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ, Ọnarebu Najeem Salam, sọ pe oju gbogbo awọn ti walẹ bayii, onikaluku si ti kọ ẹkọ kan tabi omiiran lori nnkan to ṣẹlẹ.

O ni awọn tu TOP ka lati le ṣe atunto to tọ ninu ẹgbẹ APC l’Ọṣun, o ni awọn n nawọ ifẹ si gbogbo awọn ti wọn ba gbagbọ pe ẹgbẹ Onitẹsiwaju ni ẹgbẹ APC.

Salam fi kun ọrọ rẹ pe onilu ko ni i fẹ ko tu, idi niyi ti awọn fi gbe igbesẹ ifẹ lati da ẹgbẹ APC pada si ipo Ọmọluabi ti ki i ṣe ojukokoro, to si ni akoyawọ to wa tẹlẹ nipinlẹ Ọṣun.

O ni gbogbo wahala to ti wa latẹyinwa ninu ẹgbẹ naa l’Ọṣun ti di afisẹyin bayii, asiko si ti to bayii lati ṣe atunto ati atunṣe to yẹ.

 

 

Leave a Reply