Ife-ẹyẹ agbaye:Morocco gbo ewuro soju Spain, wọn wọ kọta faina

James Ojo

Bo tilẹ jẹ pe orileede Naijiria ko ba wọn kopa nibi idije ife-ẹyẹ agbaye to n lọ lọwọ lorileede Quatar, sibẹ ninu idunnu ni awọn ọmọ orileede Afrika, paapaa ju lọ, awọn ololufẹ ere bọọlu kaakiri ilẹ wa wa bayii pẹlu bi ilẹ Alawọ dudu kan, Morocco, ṣe gbo ewuro soju ilẹ Spain, ti wọn si pegede nibi idije ko mẹsẹ o yọ ti wọn fi bọ fi ipele to kan. Iyẹn kọta faina, nibi idije to n lọ lọwọ ni papa iṣere Education City Stadium, to wa ni Qatar.

Orileede Spain ni wọn ba figa gbaga, awọn mejeeji ni wọn si gbiyanju lati ju ayo sile ara wọn, ṣugbọn ti ko ṣee ṣe nitori iṣapa awọn agbabọọlu ati goli orileede mejeeji.

Eyi lo fa a to fi jẹ pe ọmi ni awọn mejeeji gba titi ti aadọrun-un iṣẹju ti wọn lo lori papa fi pari.

Lẹyin ti ko si ẹni to jawe olubori, to si pọn dandan fun ẹni kan lati lọ ni wọn ba tun bẹrẹ ọgbọn iṣẹju mi-in. Wọn tun gba eleyii naa titi, ko tun si ẹni to gba bọọlu wọnu ile ara wọn.

N lo ba di goli si goli, eyi ti wọn n pe ni pẹnariti. Awọn agbabọọlu kọọkan ni yoo maa gba bọọlu si awọn goli, goli orileede to ba si mu bọọlu yii ni yoo gbẹyẹ lọwo alatako wọn.

Niṣe ni idunnu si ṣubu lu ayọ nigba ti goli Morocco, Yassine Bounou, mu ayo mẹtẹẹta ti awọn ọmọ orileede Spain gba si awọn rẹ. N lariwo ba sọ. Pẹlu ami-ayo mẹta si odo ni Morocco fi gbẹyẹ lọwọ Spain.

Igba akọkọ si niyi ti Morocco yoo wọ ipele to kan, iyẹn kọta faina, latigba ti wọn ti n kopa ninu ifẹ-ẹyẹ agbaye.

Awọn ọmọ orileede naa ko le pa idunnu wọn mọra fun aṣeyọri nla yii, niṣe ni ẹrin si gba ẹẹkẹ wọn, bakan naa ni awọn ọmo ilẹ Afrika yooku naa n ba wọn yọ.

Tẹ o ba gbagbe, orileede Cameroon, Ghana ati Senegal wa ninu awọn to ti kopa ninu idije ere bọọlu to n lọ lọwọ ọhun, ṣugbọn ti wọn fidi-rẹmi.

Leave a Reply