ICPC mu olorin taka-sufee nni, D’banj, fẹsun jibiti

Faith Adebọla

Inu wahala nla ni ọkunrin olorin taka-sufee ilẹ wa to gbajumọ daadaa nni, Ọladapọ Oyebanji ti gbogbo eeyan mọ si D’banji, wa bayii o. Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku pẹlu awọn ẹsun mi-in to ba jẹ mọ iwa ọdaran, Independent Corrupt Practices and other Related Offences Commission (ICPC), lo mu ọkunrin naa, o si wa lakata wọn titi asiko ti a n kọ iroyin yii to n ran wọn lọwọ lori ẹsun lilu ijọba ni jibiti ti wọn fi kan an.

ALAROYE gbọ pe wọn ti n dọdẹ ọkunrin naa tipẹ, wọn ti fiwe pe e pe ko waa ṣalaye awon iwa jibiti kan ti ileeṣẹ naa tuwee kan, ti wọn si ba ọwọ ọkunrin yii nibẹ, ṣugbọn ti ko da wọn lohun.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni wọn ka a mọ kọna, ti wọn si fipa gbe e lọ si ileeṣẹ ajọ naa to wa niluu Abuja. Wọn ni ọkunrin naa ko owo ti ijọba apapọ ya sọtọ lati maa fun awọn ọdọ ti ko niṣe lọwọ lati fi ro wọn lagbara ki wọn le maa wa nnkan ṣe ti wọn n pe ni N-Power, eyi tijọba apapọ da silẹ lọdun 2016 jẹ.

A gbọ pe awọn oṣiṣẹ ijọba kan ni wọn jọ lẹdi apo pọ pẹlu ọkunrin olorin to gbajumọ bii iṣana ẹlẹẹta yii, ti wọn si lọọ ko awọn orukọ adamọdi awọn eeyan ti ko si ẹni to n jẹ bẹẹ sinu iwe ti wọn fi n sanwo fun awọn to n janfaani eto yii si. Bayii ni awọn eeyan naa pẹlu awọn ti wọn jọọ lẹdii apo pọ lati ṣiṣẹ buruku yii gba obitibiti miliọnu to jẹ owo ti awọn ọdọ kan iba fi maa ṣanfaani, ti wọn si fi n ṣe ararindin.

ALAROYE gbọ pe nigba ti wọn yoo wadii owo naa lọ wadii rẹ bọ, akaunti D’banj ni wọn n san owo naa si. Eyi lawọn ICPC ṣe pe e pe ko waa ṣalaye ohun to mọ nipa rẹ, ṣugbọn ọkunrin naa ko jẹ ipe ileeṣẹ yii. Lẹyin ọpọlọpọ lẹta ti wọn ko si i ti ko si dahun ni wọn ba lọọ duro de e lẹsẹ-o-gbeji, wọn si gbe e janto lọ sileeṣẹ wọn niluu Abuja. Nibẹ ni wọn ti n fọrọ po o nifun pọ lati mọ bi iṣẹlẹ naa ṣe waye ati ipa to ko nibẹ. Lẹyin eyi ni wọn ni ọdọ awọn ni yoo wa fungba diẹ, ko ni i le lọ sile.

D’banji ni ki wọn fun oun ni beeli lori pe gbajumọ ni oun, oun ko le sa lọ. Ṣugbọn awọn oṣiṣẹ ọba naa ni awọn ko le fun un ni beeli, nitori ko si ẹri pe ti awọn ba fun un, yoo pada yọju pẹlu bi awọn ti ṣe fiwe pe e lọpọ igba, ṣugbọn ti ko da awọn loun yii.

Wọn ni o ṣee ṣe ki ICPC lọ si kootu lati gba iwe aṣẹ to yẹ labẹ ofin ki wọn le ni anfaani lati fi ọkunrin naa sọdọ wọn kọja akoko ti ofin la kalẹ titi ti iwadii ti wọn n ṣe yoo fi pari.

 

Leave a Reply