Ileeṣẹ Quickteller Paypoint fun awọn alagbata wọn lẹbun rẹpẹtẹ

Jọkẹ Amọri

Bii ẹgbẹrun kan awọn alagbata ileeṣẹ Quickteller Paypoint  ni wọn ṣe koriya fun lati fi imọriri wọn han fun aduroti ati aapọn wọn lọjọ keji, oṣu Kejila, ọdun 2022 yii.

Ileeṣẹ Quickteller Paypoint fun awọn eeyan naa lẹbun ọlọkan-o-jọkan lati mọ riri iṣẹ takun-takun ti wọn ti ṣe pẹlu iṣotitọ fun wọn. Ninu eto pataki kan ti wọn gbe kalẹ, eyi ti wọn pe ni ‘Double Up Promo’ ni wọn ti pese awọn ẹbun naa. Latinu oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, lawọn eeyan ti n kopa lati jẹ ẹbun, bẹẹ ni ileeṣẹ naa n ṣe aṣayan awọn ti wọn kunju oṣuwọn ti wọn maa fi oniruuru ẹbun da lọla.

Marun-un lara awọn ti wọn jẹ ẹbun naa, Bamidele Aminat, Ishaya Galion, Ayinla Habeeb, Edozie Joy, ati Ilonwa Peter  ṣabẹwo si ọgba ileeṣẹ Quickteller Paypoint lati gba ẹbun wọn tayọ-tayọ.

Lasiko to n sọrọ nibi eto naa, Maneja to n mojuto ọja tita nileeṣẹ ọhun, Bunmilọfẹ Akingbọla, sọ pe ẹbun ti wọn fun awọn onibaara awọn yii jẹ ọna lati fi imọriri han fun bi wọn ṣe sapa, ti wọn si tẹpẹlẹ mọ jijẹ kawọn araalu mọ iwulo ati anfaani lilo ikanni wọn fun ka-ra-ka-ta wọn.

O ni: “Olori erongba wa ni lati jẹ kawọn eeyan, paapaa ju lọ, awọn ti wọn wa lawọn ibi ti ko fi bẹẹ si ileeṣẹ okoowo, tubọ lominira, ki wọn si lanfaani lati ṣe ọrọ-aje wọn pẹlu irọrun, inu wa si dun gidi pe ọpọ lo n dara pọ mọ wa, ti wọn n ba awọn ejẹnti wa ṣiṣẹ kaakiri orileede yii. Loni-in,  a n fun awọn ejẹnti ti wọn poju owo yii lẹbun lati tubọ mu ki igbe aye wọn larinrin si i.”

Ṣe inu ẹni ki i dun ka pa a mọra, ọpọ lara awọn ti wọn jẹ ẹbun naa ni idunnu han loju wọn, wọn si dupẹ lọwọ ileeṣẹ Quickteller Paypoint  fun bi wọn ṣe ranti wọn, ti wọn si mọyi ipa ti wọn ko ninu idagbasoke eto okoowo ati inawo yika orileede yii. Ninu wọn tun sọrọ lori anfaani ati ominira ti ṣiṣe ejẹnti fun ileeṣẹ naa ti mu ba awọn, wọn ni ajọṣe to n mu ere gidi wa lawọn ni latigba ti awọn ti dara pọ mọ wọn.

Leave a Reply