Lẹyin ti Pasitọ Joshua fipa ba obinrin kan sun tan lo fun un lọrun pa

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ọkunrin kan to pera ẹ lojiṣẹ Ọlọrun kan, Pasitọ Joshua Oyebọde, ti dero atimọle awọn ọlọpaa n’Ibadan bayii. Ẹsun ọdaran nla nla meji ni wọn fi kan an, wọn lo paayan, o tun fipa ba ọmọọlọmọ laṣepọ karakara.

Pasitọ Joshua, ẹni aadọta ọdun, ni wọn lo fi ọmọbinrin ẹni ọdun mejilelogun kan to n jẹ Bukọla Ajala pamọ sinu ile ẹ fun ọpọlọpọ ọjọ, to si n ko ibasun fun un nibẹ lojoojumọ.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, ibẹru pe Bukọla le tu aṣiri iṣẹlẹ yii lo mu pasitọ tan ọmọbinrin naa lọ sinu igbo, to si fun un lọrun pa sibẹ.

Ṣugbọn ọrọ ẹruuku to pera ẹ ni ojiṣẹ Ọlọrun yii ko yatọ si ọrọ awodi oke to ro pe awọn to wa nisalẹ ko ri oun. Idi ni pe ohun ti pasitọ ṣe ninu igbo, to ro pe ẹnikankan ko mọ, aṣiri ọhun han sawọn eeyan kan, wọn si fi iṣẹlẹ naa to awọn agbofinro leti lagọọ ọlọpaa to wa niluu Owode, nitosi Ogbomọṣọ, nipinlẹ Ọyọ.

Nigba to n ṣafihan afurasi ọdaran naa fawọn oniroyin n’Ibadan lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Adebọwale Williams, sọ pe lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ni jagunlabi tan ẹni-ẹlẹni lọ sinu igbo, to si fun un lọrun pa.

CP Williams, ẹni to sọrọ lorukọ SP Ọṣinfẹṣọ, ti i ṣe Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, sọ pe, “Ọkunrin to pera ẹ ni pasitọ yii ba obinrin yẹn mulẹ pe ẹnikẹni ko gbọdọ tu aṣiri ohunkohun to ba ṣẹlẹ laarin awọn sita fun ẹda Ọlọrun kan.

Bo ṣe di ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun yii, pasitọ ri i pe Bukọla n palẹ ẹru rẹ mọ, ẹru ba a pe niṣe lọmọbinrin naa n sa lọ, o si ṣee ṣe ko lọọ tu aṣiri oun fun gbogbo aye. Idi niyẹn to ṣe tan an lọ si ọna jinjin, to si fun un lọrun pa lati bo ara rẹ laṣiiri”.

Ni kete ti iwadii awọn ọlọpaa ba ti pari lori iṣẹlẹ yii ni wọn yoo foju afurasi ọdaran to pera ẹ ni pasitọ yii ba ile-ẹjọ gẹgẹ bi awọn agbofinro se sọ.

Leave a Reply