Wọn yan ọmọ Yoruba gẹgẹ bii akọwe agba nipinlẹ Anambra 

Monisọla Saka

Anambra, Ọjọgbọn Charles Soludo, ti fi apẹẹrẹ rere lelẹ ninu eto iṣelu ilẹ Naijiria, pẹlu bi ọmọ Yoruba kan to wa lati ipinlẹ Ọṣun, Ọgbẹni Adebayọ Ọjẹyinka, ati ọmọ bibi ipinlẹ Abia kan, Joachim Achor, ṣe wa ninu awọn mejidinlogun to ṣẹṣẹ yan sipo akọwe agba kaakiri awọn ileeṣẹ ijọba ipinlẹ ọhun.

Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni Agbẹnusọ gomina lori iroyin, Christian Aburime, sọrọ naa di mimọ ninu atẹjade to fi sita.

O ni ki i ṣe pe gomina ṣadeede yan awọn eeyan yii pẹlu ifẹ inu, bi ko ṣe bi kaluku wọn ṣe ṣe daadaa si, paapaa lẹyin ti wọn ṣe ayẹwo ti ko ṣokunkun sẹnikẹni fun wọn.

Lara awọn igbesẹ ti wọn lo lati yan awọn eeyan yii ni idanwo ti wọn ṣe lori ẹrọ kọmputa, iwadii to jinlẹ nipa wọn ati ifọrọjomitoro ọrọ ẹni kọọkan wọn pẹlu gomina.

Aburime to ni gomina ko fi ti ẹya tabi ti ipinlẹ tiru ẹni bẹẹ ti wa ṣe ko too yan wọn, sọ ninu atẹjade naa pe, “Ifọrọjomitoro ọrọ ti wọn ṣe yii faaye silẹ fun igbọra-ẹni-ye to jinlẹ nipa afojusun ẹni kọọkan awọn ti wọn yan, ni ibamu pẹlu nnkan ti gomina n fẹ.

O ṣe pataki lati mọ pe lati ayebaye, gomina nikan lo lẹtọọ lati yan awọn akọwe agba nileeṣẹ ijọba gbogbo.

Amọ ṣa, ohun kan to yatọ lọtẹ yii ni iwadii ijinlẹ ti ko ni kọnu-n-kọhọ ninu ti gomina ṣe. Koda, wọn yan awọn mi-in ti wọn kere jọjọ lọjọ ori, amọ ti wọn jẹ oṣiṣẹ ijọba to n ṣiṣẹ takuntakun sipo.

“Igbesẹ nla ti gomina Soludo gbe pẹlu iyansipo awọn ti ki i ṣe ọmọ oniluu atawọn ti wọn wa lati ipinlẹ mi-in fi han pe ijọba yii ṣetan lati ṣawari ẹbun kaakiri orilẹ-ede yii, dipo ki wọn fi mọ lori awọn ti wọn jẹ ọmọ ipinlẹ Anambra nikan”.

O ni ohun ti eyi tumọ si ni pe ti gbogbo eeyan ni Anambra gẹgẹ bii ipinlẹ i ṣe, lai wo ti ibi ti ẹni bẹẹ ba ti wa.

O fi kun un pe bi wọn ṣe yan Ọjẹyinka lati ipinlẹ Ọṣun, jẹ igbesẹ kan gboogi, nitori bo ṣe fopin si aṣa ki wọn maa fi awọn ipo nla nla lẹnu iṣẹ ijọba silẹ fawọn ọmọ ilu nikan.

Leave a Reply