Florence Babaṣọla
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun sọ pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori wahala kan to bẹ silẹ laarin awọn ẹlẹsin Musulumi atawọn eleegun niluu Oṣogbo lọsan-an ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.
Adura nipa wahala eto aabo orileede Naijiria la gbọ pe awọn Musulumi ọhun n ṣe lọwọ lagbegbe Oluọdẹ Aranyin, n’Ita-Olookan, niluu Oṣogbo, ti wahala naa fi bẹrẹ.
Lojiji lawọn eleegun naa yọ sibẹ, ti wọn si n ju okuta lu awọn ti wọn n ṣadura, ki oloju too ṣẹ ẹ, ọrọ naa ti dariwo.
Bi awọn agbaagba mọṣalaaṣi atawọn ọdọ ṣe n beere ohun tawọn eleegun naa ri lọbẹ ti wọn fi waro ọwọ, iro ibọn ni wọn gbọ lojiji.
Ki wọn too mọ nnkan to n ṣẹlẹ, ibọn ti ba Baba Adinni mọṣalaasi naa torukọ rẹ n jẹ Moshood Salawudeen, loju-ẹsẹ ni baba naa jade laye.
Imaamu mọṣalaaṣi ọhun, Qusum Yunus, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni aago meji aabọ ọsan ọjọ Aiku, Sannde, lo ṣẹlẹ, ati pe adura pe ki Ọlọrun fopin si wahala eto aabo orileede Naijiria lawọn n ṣe lọwọ nigba tiṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.
Alukooro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, ṣalaye pe awọn ti gbọ nipa iṣẹlẹ naa ati pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori rẹ.