Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Awọn ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti fi pampẹ ofin gbe ọkunrin kan, Ṣeyi Sanṣere, lori bi wọn ṣe lo yinbọn pa Fulani darandaran kan, Muhammed Maikudi, sinu igbo to ti n daran.
Darandaran ọhun la gbọ pe wọn deedee ba oku rẹ ninu igbo ọba to wa niluu Ifira Akoko, nijọba ibilẹ Guusu, Ila-Oorun Akoko, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ ta a wa yii.
Ohun ta a gbọ ni pe awọn ọlọpaa ati ẹṣọ Amọtẹkun ti wọn tete da sọrọ naa lo fopin si rogbodiyan tí iba su yọ latari iṣẹlẹ ọhun.
Olori awọn Hausa/Fulani lagbegbe Ifira Akoko, Ọgbẹni Bala Umar, to ba awọn oniroyin sọrọ ni awọn agbofinro fidi rẹ mulẹ ninu iwadii wọn pe ṣe ni afurasi ọhun tọpasẹ oloogbe ẹni ọdun mẹrinlelogun ọhun lọ sinu igbo to ti n daran, to si yinbọn pa a.
O ni ibi to fara pamọ si lẹyin to ṣiṣẹ ọwọ rẹ tan lawọn ẹsọ alaabo ti wọ ọ jade, ti wọn si mu un lọ si teṣan ọlọpaa to wa ni Ifira.
Bala ni oun ti pẹtu sọkan awọn Fulani agbegbe naa ki wọn ma ṣe dabaa ati gbeja ara wọn.
Alakooso ẹsọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, ni ọrọ iku Muhammed ko lọwọ ija to saaba maa n waye laarin awọn agbẹ ati darandaran agbegbe naa ninu.
O ni ọkunrin ọlọdẹ naa nikan lo le sọ ni pato idi to fi huwa to hu naa.
A gbọ pe wọn ti fi afurasi naa sọwọ si olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa l’Akurẹ, nibi ti iwadii ti n tẹsiwaju lori ẹsun ti wọn fi kan an.