Wọn yọ DPO yii niṣẹ, awọn ọmọọṣẹ ẹ lo ko ba a

Adewale Adeoye

 Mẹrin lara awọn ọlọpaa ti wọn n ṣiṣẹ ni teṣan ọlọpaa kan to wa niluu Ogudu, nipinlẹ Eko, ni wọn ti fọwọ ofin mu bayii, ti wọn si n jẹjọ lori iwa ẹsun ọdaran ti wọn fi kan wọn pe ṣe ni wọn fọwọ lile mu Ọgbẹni Emmanuel Nnawuihe, ti wọn si gba ẹgbẹrun lọna mẹtale-laaadọjọ Naira (N153,000) ninu akanti rẹ lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹta, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, ni nnkan bii aago mẹta aabọ ọsan ọjọ naa, ko too di pe wọn fi i silẹ pe ko maa lọ.

Ẹsun yii lawọn alaṣẹ ileẹṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko sọ pe ki i ṣohun to daa rara, ti ijiya nla si wa fẹni to ba ṣe bẹẹ.

ALAROYE gbọ pe wọn tun ti yọ D.P.O teṣan tawọn ọlọpaa mẹrẹẹrin naa, ti n ṣiṣẹ, C.S.P Celestina Kalu danu lẹnu iṣẹ. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o kuna lati mojuto ohun to n ṣẹlẹ lakata rẹ.

Ohun ta a gbọ ni pe ṣe lawọn ọlọpaa naa da Emmanuel duro labẹ biriiji kan bayii to wa lagbegbe Ọjọta, niluu Eko, ti wọn si sọ pe awọn fẹẹ yẹ ara rẹ ati mọto owolo nla kan ti wọn ba nidii rẹ wo nitori pe awọn fura si i pe iṣẹ ọwọ rẹ ko mọ.

Wọn yẹ ara Emmanuel wo, ṣugbọn wọn ko ba nnkan to fi han pe ọdaran ni rara lara rẹ. Lẹyin ti wọn ko ri ohun ti wọn lero ni wọn ba tun gba foonu ọwọ rẹ, wọn si yẹ ẹ wo, ninu foonu naa ni wọn ti ri i pe owo to le ni miliọnu meji Naira lo wa nibẹ, ni wọn ba sọ pe afi ki Emmanuel fun awọn lowo lara eyi tawọn ri ninu akanti rẹ yii.

Gbogbo alaye ti ọkunrin yii ṣe fawọn ọlọpaa naa pe oun kọ loun ni owo naa ko wọ wọn leti rara, niṣe ni wọn bẹrẹ si i dukooko mọ ọn pe awọn maa fimu rẹ danrin ti ko ba fun awọn lowo. Ti wọn si ti n ka oniruuru ẹsun si i lẹsẹ.

Nigba ti Emmanuel ri i pe awọn ọlọpaa naa ko mu ọrọ ọhun ni kekere rara, to si jọ pe wọn le ṣe e nijamba bi ko ba ṣe ifẹ inu wọn lasiko lo ba gba lati fun wọn niye ti wọn n beere lọwọ rẹ.

Inu akanti kan ti ki i ṣe tawọn ọlọpaa ni wọn sọ pe ki Emmanuel fowo ọhun ranṣẹ si, ki wọn ma baa tọpinpin bowo ọhun ṣe rin de ọdọ wọn.

A tiẹ gbọ pe inu akaunti Ọgbẹni Edidiong Anthony, lawọn ọlọpaa naa sọ pe ki Emmanuel sanwo ọhun si, ti wọn si ti gbowo naa pada fun un bayii.

 Ibinu pe awọn ọlọpaa ọhun yan-an jẹ lo mu ki Emmanuel lọọ fọrọ naa to awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ilu Eko leti, ti Kọmiṣana ọlọpaa ipinlẹ Eko, C.P Idowu Ọmọhunwa, si paṣẹ fawọn ọmọọṣẹ rẹ pe, ki wọn ṣewadii daadaa nipa ẹsun ti Emmanuel fi kan awọn ọbayẹjẹ ọlọpaa naa.

Emmanuel atawọn ọlọpaa kan ti wọn n ṣewadii nipa ọrọ naa ni wọn lọ si teṣan Ogudu, ti Emmanuel si tọka si meji lara awọn ti wọn gbowo lọwọ rẹ. Loju-ẹsẹ ni wọn ti fọwọ ofin mu wọn lọ solu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Ikeja, fun ẹkunrẹrẹ iwadii nipa ohun tawọn agbofinro ọhun ṣe.

Leave a Reply