Wọn yọ orukọ Portable kuro lara awọn to fẹẹ gba awọọdu, wọn ni woroworo ẹ ti pọ ju

Faith Adebọla, Eko

Latari bo ṣe n fẹnu ja waya kiri, to sọ pe oun loun da ẹgbẹ okunkun One Million Boys silẹ l’Ekoo, eyi tijọba tori ẹ n wa a l’Abuja, to si tun lọọ halẹ mọ awọn onkọrin ẹlẹgbẹ rẹ lori ẹrọ ayelujara, gbajugbaja onkọrin igbalode Zah Zuh Zeh nni, Habeeb Okikiọla, ti inagijẹ rẹ n jẹ Portable, ti n jere abuku lọkan-o-jọkan. Onkọrin naa iba gba awọọdu pataki meji laipẹ sasiko ta a wa yii, ṣugbọn ni bayii, wọn ti yọ orukọ rẹ kuro lara awọn to fẹẹ gba awọọdu naa bii ẹni yọ jiga, wọn ni ko kun oju oṣuwọn to.

Isọri ẹni to fẹẹ gba awọọdu olorin igbalode to laluyọ lọdun 2022, Rookie of the Year, ati awọọdu onkọrin igboro to daa ju lọ lọdun 2022, Best Street-Hop Artiste ni wọn to orukọ Portable si tẹlẹ, ṣugbọn ninu atẹjade awọn ti wọn ṣeto awọọdu naa, eyi ti ajọ The Headies to ṣeto ayẹyẹ naa fi lede lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Keje yii, wọn ti pa orukọ Habeeb rẹ, ko si lara wọn mọ.

Ṣe lọjọ Aiku, Sannde to kọja yii, ni ọrọ ti Portable kọ soju opo Instagraamu rẹ bẹrẹ si i ja ranyin, to ni ẹnikan ki i ba yimi-yimu du’mi lọrọ awọọdu naa jẹ foun o, tẹnikẹni ba fi gba awọọdu naa mọ oun lọwọ, iku ni tọhun maa fi ṣefa jẹ. Bo ṣe kọ ọ sibẹ gan-an ni pe: “Awọọdu mi leyi o, tẹlomi-in ba gba a, ma a ni ki wọn pa tọhun ni, ma a ni ki wọn pa ẹni naa, bawọn to ṣeto awọọdu yii ba fi gbe e fun ẹlomi-in, wọn maa ku ni – Emi ni Habeeb Okikiọla.”

Eyi lawọn to ṣeto awọọdu naa ro papọ mọ iwa abuku ti ọnkọrin naa ti n hu, ati ọrọ idunkooko-mọ-ni to kun ẹnu rẹ, ti wọn fi sọ ninu atẹjade kan ti wọn fi lede lọjọ Tusidee naa pe: “O dun wa lati kede pe awọn ọrọ akoba woroworo ti Ọgbẹni Habeeb Okikiọla, tawọn eeyan mọ si Portable, n sọ, ati orukọ buruku to ni lọdọ awọn ọlọpaa Naijiria ati lọdọ awọn araalu laipẹ yii, awọn oluṣeto awọọdu agbaye Headies ti pinnu lati yọ ọ kuro lara awọn to maa gba awọọdu wa ikẹẹẹdogun to maa waye laipẹ yii.”

Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ to lọ lọhun-un lọga agba patapata nileeṣẹ ọlọpaa ilẹ wa paṣẹ ki wọn wa Portable lawaa kan nibikibi to ba wa, wọn lo gbọdọ ṣalaye ọrọ to sọ ninu fidio kan to gbe jade, nibi to ti n fọwọ sọya pe oun loun da ẹgbẹ okunkun Ajah Boys ati One Million Boys silẹ l’Ekoo, to tun n fi Sammy Larry ṣẹlẹrii ara ẹ.

Ọsẹ meji ṣaaju iyẹn nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun kede pe dandan ni ki Portable yii kan naa yọju sawọn tori o lẹjọ i jẹ, latari fidio mi-in to gbe sori ẹrọ ayelujara, nibi to ti fi ara ẹ ṣe alaga idajọ, to paṣẹ fawọn ẹmẹwa ẹ pe ki wọn lu ọkunrin kan to wa lori ikunlẹ lalubami, o ni o dẹnu ifẹ kọ iyawo oun, tabi ko mọ pe iyawo oun Portable ni, tori ẹ, wọn gbọdọ lu u bii ẹni luṣọ ofi ni, wọn si lu ọkunrin naa gidi.

Bo tilẹ jẹ pe o ti yọju sileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun lẹyin naa, ti wọn si ti kilọ fun un, kaka ko san lara iya ajẹ lọrọ Habeeb Okikiọla, niṣe lo fi gbogbo ọmọ rẹ bi obinrin, lẹyẹ ba n yi lu ẹyẹ.

Leave a Reply