‘Yahoo’ lawọn eleyii n ṣe l’Ajah ti EFCC fi ko wọn

Faith Adebọla, Eko

 

 

Mejilelogun (22) ni gbogbo wọn, afurasi ọdaran ni wọn, bi wọn ṣe maa lu awọn eeyan ni jibiti lori atẹ ayelujara ni wọn n fojoojumọ aye wọn wa, idi iṣẹ buruku ọhun si lọwọ ti tẹ wọn lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

Atẹjade kan latọdọ Ọgbẹni Wilson Uwajuren to jẹ Alukoro fun ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣẹ owo mọkumọku nni, EFCC, sọ pe inu ile oniyara-pupọ kan to wa ni Terra Annex Estate, laduugbo Ṣangotẹdo, l’Ajah, nipinlẹ Eko lawọn afurasi naa fori pamọ si, ibẹ ni wọn ti n huwa apamọlẹkun-jaye wọn.

O ni aipẹ yii lawọn gba ipe latọdọ awọn araadugbo kan ti wọn fura si awọn gende wọnyi, wọn ni ki EFCC waa bawọn yẹ iṣẹ ọwọ wọn wo, lawọn ọtẹlẹmuyẹ ba bẹrẹ si i tọpasẹ awọn afurasi naa tọwọ fi ba wọn.

Orukọ wọn ni Muyiwa Adetọla, Adeolu Demilade, Abel Oriṣetimẹyin, Lekan Ademọla, Abayọmi Qudus, Isaac Chibueze, Ayẹni Ọlanrewaju, Aminu Kelvin, Ajama Patrick, and Nesta Olotu.

Awọn to ku ni Odaro Edogiawere, Ayọ Balogun, Mustapha Hassan, Musbaudeen Ọlamilekan, Adewumi Adebayo, Charles Akpene, Joshua Ugwuomore, Ayẹni Damilola, Ogundare Kayọde, Kara Uzuegbu, Akindele Samuel, ati Ọladimeji Ashiru.

Alukoro EFCC ni gbogbo awọn ti a darukọ yii ti n ran awọn ọtẹlẹmuyẹ ajọ naa lọwọ ninu iwadii wọn. Awọn irinṣẹ bii kọmputa alagbeletan, foonu ati awọn nnkan mi-in ni wọn ka mọ wọn lọwọ.

O ni tiwadii ba ti pari, gbogbo wọn lawọn maa wọ de kootu,

 

 

Leave a Reply