Faith Adebọla
Baba agbalagba kan, Tajudeen Alao Yẹkinni, tọjọ ori rẹ yoo ti sun mọ ọgọta ọdun, ti tọwọ ara rẹ bọ ṣọọlọ bayii, pẹlu bo ṣe n kawọ pọnyin rọjọ niwaju adajọ Majisireeti Kootu Karun-un, to wa ni Samuel Ilori Courthouse, lagbegbe Ọgba, nitosi Ikẹja, nipinlẹ Eko.
Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹfa, oṣu Karun-un, ọdun yii, lawọn agbofinro foju baba naa bale-ẹjọ fun ẹsun ole jija, ati igbimọ-pọ lati huwa buruku.
Nigba ti wọn pe ẹjọ rẹ, afurasi ọdaran to wọ buba ati ṣokoto aṣọ ankara dudu kan sọ fun adajọ ninu koto ijẹjọ to wa pe oun ko gbọ ede oyinbo, eyi lo mu ki akọwe kootu dide lati ka ẹsun rẹ si i leti lede Yoruba.
Ẹsun akọkọ lọ bayii:
Iwọ, Ọgbẹni Tajudeen Alao Yẹkinni, ni agbegbe Ọkọta, nijọba ibilẹ Amuwo Ọdọfin, to wa labẹ aṣẹ kootu yii, gbimọ-pọ pẹlu awọn afurasi kan ti a ṣi n wa lọwọ lati jale, leyii to lodi sofin iwa ọdaran ipinlẹ Eko, ṣe bẹẹ ni abi bẹẹ kọ?
O ni, ‘bẹẹ kọ’.
Akọwe kootu tun ka ẹsun keji si i leti lede Yoruba, o ni:
Ni ọjọ kan naa, ni agbegbe kan naa, to jẹ ayika ile-ẹjọ yii, iwọ ati awọn kan ti a ṣi n wa bayii gbimọ-pọ lati ji kọntena to ko sẹsimẹsi ti owo rẹ to bii miliọnu marundinlọgọta (N55m), to jẹ ti ileeṣẹ Oṣun Property and Agric Commodities, ni eyi to lodi si ofin, bẹẹ ni abi bẹẹ kọ?
Eyi ti baba yii iba fi dahun, niṣe lo ṣoju misin-misin, to si tẹwọ si adajọ, o ni sim card ni mo ra o, Oluwa mi, siimu kaadi lemi ra, mi o ko ẹru.
Eyi lo mu ki adajọ bẹrẹ si i bii leere pe ọwọ ta lo ti ra sim card? Yẹkinni fesi pe: Ọwọ ọkunrin kan bayii ni, o ti sa lọ.
Adajọ tun bi i leere pe: Ki lo de to o fi lọ sile ibi ti wọn ti n ta sim card, ko o lọọ ra a nibẹ, to fi jẹ ọwọ ẹni ti o ko mọ ri lo ti ra sim card. Amọ ko fesi, niṣe lo n ṣe bii ẹni to fẹẹ bu sẹkun.
Adajọ tun ni, iru sim wo lo ra? O si fesi pe MTN ni.
Adajọ ni nibo waa lẹni to o ra sim lọwọ ẹ wa, ati pe nibo lo ti mọ onitọhun ri tẹlẹ, olujẹjọ si fesi pe oun ko mọ ọn ri tẹlẹ, o kan waa ba oun ni pe ṣe oun fẹẹ ra sim, oun si loun fẹ, loun ba ra a lọwọ ẹ, ati pe onitọhun ti sa lọ bayii.
Adajọ ni. ‘ṣe o fẹẹ sọ fun mi pe oo mọ ibi ti wọn ti n ta sim l’Ekoo yii, ṣe o ṣẹṣẹ de Eko ni? O o gbọ MTN ri? O o gbọ glo ri, oo dẹ gbọ Airtel ri?’ O loun gbọ ọ.
Adajọ ni ṣebi awọn to n ta sim card niwọnyẹn? Eeyan loun fẹẹ ta sim card, ko o waa ra a, iwọn naa dẹ ko owo fun un! Lori sim card yẹn, NIN ta lo wa lori ẹ, orukọ wo ni wọn fi rẹjista ẹ? Iwọ naa feti si ara ẹ, abi? Gbọ ara ẹ, ṣe ọrọ to o n sọ yii b’ọgbọn mu?
Bi adajọ ṣe n beere awọn ibeere yii ni gbogbo kootu n wo afurasi yii tiyanu-tiyanu, awọn mi-in si n kaaanu ẹ. Amọ nigba ti adajọ beere pe ta ni lọọya rẹ, o loun ko ni lọọya, oun o rowo gba lọọya, ni gbogbo kootu ba kọ haa!
Lẹyin iṣẹju diẹ, adajọ paṣẹ pe oun yọnda beeli fun ọkunrin naa pẹlu miliọnu kan aabọ Naira (N1.5m), o si gbọdọ wa oniduuro meji ti wọn ni iye owo yii lọwọ ati dukia to jọju layiika kootu, aijẹ bẹẹ, ki wọn ṣi lọọ fi i pamọ si ọgba ẹwọn titi di ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Karun-un, ti igbẹjọ yoo maa tẹsiwaju.