Eyi ni bi Auxiliary, ọga awọn onimimọ ipinlẹ Ọyọ ṣe dero atimọle

Ọlawale Ajao, Ibadan

Afaimọ lalakooso gbogbo awakọ ero nipinlẹ Ọyọ nigba kan ri, Alhaji Mukaila Lamidi, ẹni ti gbogbo aye mọ si Auxilliary, ko tun ni i dero ẹwọn lẹẹkan si i pẹlu bi awọn agbofinro ti ṣe fi panpẹ ọba gbe e, to si ti dero atimọle bayii.

Ni nnkan bii aago mẹrin irọlẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ keje, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, lawọn ọlọpaa abẹ́nú, ti wọn n pe ni Department of State Services (DSS), lọọ fi panpẹ ọba gbe e nile ẹ to wa laduugbo Olódó, n’Ibadan, ti wọn si sọ ọ sinu ahamọ wọn fun ẹsun ti a ko ti i mọdi ẹ titi ta a fi pari akojọ iroyin yii.

Nigba ti awọn ọlọpaa mu ọga awọn onimọto yii lọjọ kẹjọ, oṣu Kọlanla, ọdun 2022 naa, irọlẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, naa lo bọ si. Nile Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, la si gbọ pe wọn ti mu un lọjọ naa ki wọn too pada gba beeli ẹ nitori oun ni Gomina.Makinde fi ṣe alaga igbimọ to n dari awọn awakọ ero nipinlẹ naa lasiko ọhun.

Ṣugbọn lọjọ kẹta rẹ, ti i ṣe Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Kọkanla, ọdun naa ni CP Adebọwale Williams, ti i ṣe ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ nigba naa, pada gbe e lọ si kootu lati jẹjọ awọn ẹsun ọdaran ti wọn fi kan an niwaju adajọ.

Ọkan ninu awọn ẹsun ọhun ni pe lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtala, oṣu Kọkanla, ọdun 2022, oun pẹlu awọn afurasi ọdaran kan jọ gbimọ-pọ lati ba dukia onidukia jẹ laduugbo kan ti wọn n pe ni Igboọra, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ariwa Ibadan.

Bo tilẹ jẹ pe ẹṣẹ ti Auxiliary ṣẹ ti awọn DSS fi mu un lọtẹ yii ko ti i han si gbogbo aye, akọroyin ALAROYE gbọ pe bo ṣe dero atimọle bayii ko ṣẹyin awọn ọrọ to sọ ninu ifọrọwọrọ kan to ṣe pẹlu oniroyin ileeṣẹ redio aladaani kan n’Ibadan, nibi to ti fibinu sọko ọrọ ranṣẹ si Ọtunba Ṣẹyẹ Famojurọ to jẹ ẹyinloju Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde ti i ṣe gomina ipinlẹ Ọyọ, ti eerun ọrọ ọhun si ta ba gomina gan-an funra alára.

Ninu ifọrọwerọ ọhun lo ti sọ pe ọkunrin ti awọn eeyan saaba maa n pe ni Ọtunba Ṣẹyẹ yii lo ran awọn agbofinro waa ka oun mọle lodun 2023 to kọja yii, ti wọn fi ko owo ati ọpọlọpọ nnkan ini oun lọ, ti wọn si tun ba ileetura oun to n mowo wọle fun oun jẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Nigba ti Gomina Makinde n ba Ọọni sọrọ lọjọ kan, o sọ fun Ọọni pe oun ko ba mi ja, ọrẹ mi (Ọtunba Famojurọ) lo n ba mi ja. Ṣẹyẹ o si le ṣe kọja ohun to ṣe yẹn lẹyin to ran awọn ọlọpaa waa ka mi mọle ti wọn ba awọn dukia mi jẹ, ti wọn si tun gbẹsẹ le gbogbo owo mi to wa ni banki. Ileetura mi, Diamond Hotel, to bajẹ yẹn, mo ti kọ ọ lati ọdun mẹẹẹdogun sẹyin ko too di pe wọn de ijọba.

“Bo pẹ boya, Ṣẹyẹ yoo gba ilu wọn lọ n’Ijẹṣa, emi ati Ṣeyi ni yoo jọ ku n’Ibadan”.

Nigba to n dahun ibeere mi-in ti wọn bi i lọjọ naa lọhun-un, ọga awọn awakọ ero ipinlẹ Ọyọ yii sọ pe, “ta ni n jẹ Ọtunba? Ọtun osi! Boya oun ni gomina ni, boya Ọga (Makinde) ni, a o kuku mọ.

‘’Eeyan to da ọrọ mi ru ko ju Ọtunba Joseph Ṣẹyẹ Famojurọ lọ. Mo si gbọ pe gbogbo ohun to ṣe fun mi, Ṣeyi (Gomina Makinde) mọ si i. Ẹ maa wo o, eeyankeeyan to ba yan ẹnikan jẹ, bo pẹ boya, ti onikaluku yoo ba a”.

“Ọpọlọpọ nnkan ni wọn yoo la kọja ki ijọba wọn too pari, ọpọlọpọ nnkan lémi naa yoo la kọja ki ijọba wọn too pari”.

Titi ta a fi pari akojọ iroyin yii l’Auxiliary ṣi wa lakata awọn ọlọpaa abẹnu, ko si jọ pe wọn yoo tete fi i silẹ lọtẹ yii, nitori ALAROYE gbọ pe wọn n ṣewadii awọn ẹsun iwa ọdaran kan ti wọn ti fi kan an sẹyin, o si ṣee ṣe ki wọn tori ọrọ naa gbe e lọ sile-ẹjọ

 

Leave a Reply