Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ile-ẹjọ giga kan to wa nipinlẹ Ekiti, eyi ti Onidaajọ Lẹkan Ogunmoye n dari ti paṣẹ pe ki wọn lọọ so awọn ọdaran mẹta kan rọ titi ti ẹmi yoo fi bọ lara wọn. Bakan naa ni ile-ẹjọ naa tun pasẹ pe ki ẹni kan maa lọ si ẹwọn gbere fun ṣiṣe ẹgbẹ okunkun.
Awọn ọdaran naa ni wọn ko wa siwaju ile-ẹjọ giga naa ni ọgbọnjọ, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2020, pẹlu ẹsun oniga marun-un to ni i ṣe pẹlu igbimọ-pọ ṣiṣẹ ibi, idigunjale, gbigba ẹru ole silẹ ati siṣe ọmọ ẹgbẹ okunkun.
Gẹgẹ bi iwe ẹsun ti wọn fi kan awọn ọdaran, Babalọla Bidemi, ẹni ọdun mejilelọgbọn (28), Akinwale Oluwaseun, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn (26), Oyebamiji Sọla, ẹni mokanlelọgbọn (31), Jimoh Azeez, ti apeja rẹ n jẹ Aṣela, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn ati Ogunlade Babatunde, ẹni ọdun mejilelọgbọn (28) naa ṣe sọ, ọjọ kẹta, oṣu Kẹwa, ọdun 2018, ni wọn gbimọ-pọ lati digunjale laduugbo Oke-Oniyọ, ni Ado-Ekiti.
Agbefọba ni, “Awọn ọdaran wonyi, digun ja Arabinrin Tijani Ọmọwum ati Ogunrinde Olumide lole. Wọn gba ẹrọ ilewọ wọn, ẹrọ amóhùnmáwòrán, aago ọwọ ẹgba ọrun, aṣọ, ṣokoto, owo to to bii ilaji miliọnu Naira atawọn ẹru miiran lọwọ rẹ.
“Lakooko ti wọn fi ṣe ọsẹ nla yii, igi, ada ati ibọn ni wọn ko dani, ẹsẹ wọnyi lodi sofin idigunjale ati lilo ohun ija oloro lọna to lodi si ofin kẹfa orilẹ-ede Naijiria, eyi ti wọn ṣe atunkọ rẹ l’ọdun 2017”
Nigba to n jẹrii nile-ẹjọ, ọkan lara awọn ti wọn digun ja lole ṣalaye pe, “Oju oorun ni mo wa ninu ile mi ni deede aago mẹwaa alẹ ọjọ naa, sadeede ni mo gbọ ti ẹnikan kan ilẹkun mi, nigba ti mo laju ni mo ri awọn ọkunrin meji ti wọn ko igi, ada ati ibọn lọwọ, wọn lu mi bii ẹni lu baara, wọn tun ni ki n doju bolẹ.
“Wọn ko gbogbo dukia mi bii tẹlifiṣan, ẹrọ ilewọ, ati owo to to bii ilaji miliọnu kan, wọn tun fi agbara wọ mi jade nihooho, wọn fẹẹ fipa ba mi lo pọ. Ọkan lara awọn ole naa sọ pe oun ko ni i gba ki wọn fipa ba mi lo pọ. Aarọ ọjọ keji ni mo lọọ fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti.”
Lati fi idi ẹjọ rẹ mulẹ ṣinṣin, Agbefọba ile-ẹjọ naa, Arabinrin Dọlapọ Oyewọle, pe ẹlẹrii marun-un, bakan naa lo tun ko iwe ti wọn fi gba ohun silẹ lẹnu awọn ọdaran naa lakooko itọpinpin awọn ọlọpaa pẹlu apo igbo nla kan ti wọn gba lọwọ awọn ọdaran naa gẹgẹ bii ẹsibiiti silẹ.
Awọn ọdaran naa ja fitafita lati ri i pe wọn bọ ninu ẹsun ti wọn fi kan wọn pẹlu bi agbẹjọro wọn, Ọgbẹni Adeyinka Ọpalẹkẹ ṣe sọ pe onibaara oun ko jẹbi ẹsun naa.
Ṣugbọn ninu idajọ rẹ, Onidaajọ Lekan Ogunmoye sọ pe, “Pẹlu gbogbo ẹri to wa niwaju ile-ẹjọ yii, agbefọba ro ẹjọ rẹ yekeyeke, o si fi idi rẹ mulẹ ṣinṣin. Ọdaran akọkọ, Babalọla Bidemi, mọ pe ẹrun ti oun gba silẹ lọwọ awọn ẹgbẹ rẹ yooku jẹ ẹru ole. Nidii eyi, ki ọmọkunrin naa lọọ ṣẹwọn ọdun mẹwaa pẹlu iṣẹ aṣekara. Bakan naa ni ki ọdaran keji, Akinwale Oluwaṣeun, maa lọ layọ ati alaafia.
‘‘Ṣugbọn ni ti awọn ọdaran kẹta, ikẹrin ati ikarun-un, Oyebamiji Ṣọla, Jimoh Azeez ati Ogunlade Babatunde, ile-ẹjọ yii ri i pe wọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn. Nidii eyi, ki wọn lọọ yẹgi fun awọn ọdaran mẹtẹẹta yii titi ti ẹmi yoo fi bọ lẹnu wọn.
Ki Ọlọrun foriji ẹmi wọn”.