Ọba Ọlakulẹyin fitan balẹ, eyi lohun to ṣe nile Olubadan to waja

Ọlawale Ajao, Ibadan

Pẹlu bi ipapoda Olubadan kan ṣe maa n jẹ anfaani fun igbakeji rẹ lati gori itẹ gẹgẹ bii Olubadan tuntun, to jẹ pe eto iwuye ati bi awọn naa yoo ṣe gori itẹ lẹni ti ipo naa ba kan maa n mojuto lai bikita nipa ibanujẹ awọn ẹbi ọba to waja, iṣẹlẹ tuntun wọnu itan Ibadan lọjọ Ajẹ, Mọnde, ọjọ kẹfa, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, nigba ti ẹni to kan bayii lati gori itẹ Olubadan, Ọba Owolabi Ọlakulẹhin, ṣabẹwo si awọn ẹbi Olubadan to waja, Ọba Mohood Lekan Balogun.

Oun pẹlu mẹta ninu awọn igbimọ Olubadan, ni wọn jọ ṣabẹwo ọhun si awọn ẹbi Ọba Balogun, lagboole wọn to wa ni Aliiwo. Osi Balogun ilẹ Ibadan, Ọba Lateef Gbadamọsi Adebimpe, lo ṣaaju awọn to kọwọọrin pẹlu Olubadan lọjọ naa. Orukọ awọn meji yooku ni Aṣipa Olubadan, Ọba Abiọdun Kọla-Daisi ati Ọba Kọlawole Adegbọla, ti i ṣe Aṣipa Balogun ilẹ Ibadan.

Nigba to n ṣalaye idi to ṣe ṣabẹwo naa, Ọba Ọlakulẹhin, ṣapejuwe igbesẹ ọhun gẹgẹ bii eeso igi ti Ọba Balogun gbin nigba aye ẹ, nitori bi ifẹ ati iṣọkan yoo ṣe wa laarin Olubadan ati igbimọ rẹ lọba naa mu ni pataki nigba to wa laye.

O ṣeleri pe oun yoo tẹsiwaju ninu gbogbo iṣẹ rere ti ọba to waja naa fi silẹ, paapaa, nitori ifẹ ijinlẹ ati ibaṣepọ to dan mọran to wa laarin oun ati Olubadan ana naa.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Loootọ, asiko ti Ọba Balogun lo lori itẹ kere loju awa eeyan, ṣugbọn awọn ohun rere ti wọn ṣe nigba ti wọn wa lori itẹ ki i ṣe kekere. Nitori naa, ẹyin ẹbi Kabiesi ko ni lati maa banujẹ, bi ko ṣe kẹ ẹ maa dupẹ lọwọ Ọlọrun pe wọn gbe igbe aye rere, ati pe asiko ti wọn lo lori itẹ lapẹẹrẹ.

Ninu ọrọ tiẹ, Ọba Adebimpe ti i ṣe Osi Balogun ilẹ Ibadan, sọ pe ohun ti ko ṣẹlẹ ri ninu itan Ibadan lo ṣẹlẹ bayii, nitori ko ti i waye ri, pe ki ẹni ti ipo Olubadan kan lọọ ki awọn ẹbi ẹni to fi ipo naa silẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Ọba Ọlakulẹhin ko si nile, nibi ti wọn ti n toju ara wọn ni wọn wa lasiko ti Ọba Balogun papoda. Nigba ti wọn pada de lẹyin ti ara wọn ti ya tan ni wọn waa ṣabẹwo si awọn ẹbi ọba to waja yii, eyi ti iru ẹ ko waye ri.

“Ọba Ọlakulẹhin gbe igbesẹ yii lati jẹ ki wọn mọ bi ifẹ ṣe wa laarin awọn pẹlu Ọba Balogun to waja to, ati pe ifẹ naa ṣi wa sibẹ, bẹẹ ni yoo si maa wá lọ titi”.

Sẹnetọ Kọla Balogun, aburo Olubadan to waja lo gba awọn eeyan naa lalejo lorukọ idile Aliiwo.

Nigba to n fi idunnu ẹ han nipa abẹwo naa lorukọ idile Aliiwo, Sẹnetọ Balogun sọ pe, “Bi Olubadan kan ba ti waja, eto igbaradi lati jọba lẹni ti ipo naa ba kan maa n gbaju mọ, wọn ki i  roju raaye ṣabẹwo si awọn ẹbi ọba to papoda. Eyi ti Ọba Ọlakulẹhin ṣe yii lakọọkọ iru ẹ nilẹ Ibadan, nitori iru eyi ko waye ri”.

 

Leave a Reply