Ṣebi ẹyin naa n gbọ isọkusọ lẹnu ọkunrin-kukuru-biliisi

O ṣoju mi koro (Apa Kin-in-ni)

 

Bo ba jẹ gbogbo awọn gomina lo ri bii ti Benue

Bo ba jẹ bi Gomina Samuel Ortom ti ipinlẹ Benue ti ri yii ni gbogbo awọn gomina ta a ni ni Naijiria ti ri, gbogbo daamu-daabo to ba wa yii, ati idarudapọ to n lọ kaakiri ilẹ yii, a ko ni i ri i rara o, bi a ba si ri i, ko le pẹ ti yoo fi wọlẹ lọ. Ko si ohun ti awọn gomina wọnyi nilo lati ṣe ju ki wọn ba Aarẹ Muhammadu Buhari sọ ootọ ọrọ lọ. Ṣugbọn awọn ***oku-bọnabona, awọn onijẹkujẹ taara, awọn ni wọn pọ ninu awọn gomina ilẹ yii, awọn ti wọn yoo ri ododo ti wọn ko ni i le sọ, awọn naa ni wọn si n ko wa si gbogbo wahala yii. Ṣugbọn Otorm yatọ si wọn, o si yaayan lẹnu pe ọkan ninu awọn aṣaaju ẹgbẹ APC ni. Ọrọ ti awọn aṣaaju ẹgbẹ APC mi-in ko le sọ, oun sọ ọ o. O ni gbogbo iwa ti awọn Fulani n hu kiri yii, iwa ipaayan, iwa ijinigbe, iwa ifipa-ba-ni-sun, ifipa-gba-oko-oloko, o ni ijọba apapọ, labẹ Aarẹ Buhari, lo fa a, nitori ijọba apapọ ti fihan pe ẹyin awọn Fulani onimaaluu yii lawọn wa, ẹyin wọn lawọn yoo si maa wa nigba gbogbo. O ni ti ki i baa ṣe pe Buhari ati awọn eeyan rẹ ba mọ pe ipo aarẹ Naijiria ki i ṣe ipo aarẹ awọn Fulani, ti Buhari ba mọ pe oun ki i ṣe Aarẹ awọn Fulani, Aarẹ Naijiria loun, ọrọ naa ko ni i yanju lae. O ni bi awọn Fulani ba paayan, ti wọn ba jiiyan gbe, tabi wọn pa oloko nitori to ni ki wọn ma fi maaluu jẹ oko oun, o ni Buhari ko ni i sọrọ, awọn ti wọn n ba a ṣiṣẹ naa yoo yi oju si ẹgbẹ kan, wọn yoo ṣe bii ẹni pe wọn ko si niluu. Ṣugbọn ti awọn ti aburu yii ṣẹlẹ si ba mura lati gbe igbesẹ lati fiya jẹ awọn Fulani tabi lati le wọn kuro ni adugbo wọn, kia ni ijọba yoo ji dide, ohun awọn ti wọn wa lẹgbẹẹ Buhari yoo la kiakia, wọn yoo ni awọn ko le laju silẹ ki wọn le Fulani, gbogbo wa la ni Naijiria. Ọkunrin gomina yii ni ohun ti iwa Buhari ati awọn eeyan rẹ n fihan ni pe wọn lọwọ si gbogbo ohun to n ṣẹlẹ, wọn wa nidii ibajẹ yii, nitori awọn naa n ṣe atilẹyin fawọn onibajẹ ni. O ni o yẹ ki oju ti Buhari, pe o ṣe jẹ lasiko tirẹ ni nnkan kuku ri bayii, ti gbogob rẹ si bajẹ pata, ti ko si wi kinni kan, ka ma ti i sọ pe yoo ṣe nnkan kan si i. Ọrọ kan ko tun gbọdọ ju bayi lọ. Ododo ọrọ kan ko gbọdọ ju bayii lọ lẹnu aṣaaju APC to tun jẹ gomina. Bawọn gomina ati aṣaaju APC to ku ba duro gangan, ti wọn sọ eleyii fun Buhari, ṣe yoo ni oun ko gbọ ariwo bayii ni, koda ki eti rẹ ti di pata. Ṣugbọn wọn ko jẹ sọrọ, wọn ko jẹ wi kinni kan, kaka bẹẹ, wọn yoo dakẹ rọrọ, nitori onibajẹ ni wọn, ninu ibajẹ ni wọn si ti n jẹ. Ṣugbọn Ọlọrun yoo mu wọn o, yoo mu wọn nigba to ba ya, awọn gomina ati ẹyin aṣaaju APC ti wọn ko le lanu sọrọ lori aburu awọn Fulani nilẹ Yoruba ati kari Naijiria, Ọlọrun yoo mu wọn o. Nigba ti idajọ Ọlọrun ba si de, gbogbo aye ni yoo ri i pe idajọ Ọlọrun ju tawa eeyan lọ.

 

 

Ṣebi ẹyin naa n gbọ isọkusọ lẹnu ọkunrin-kukuru-biliisi

Ọkan lara awọn abanilaye jẹ, lara awọn ti wọn n ko ba Buhari, ti wọn si n da nnkan rẹ ru ni Gomina Kaduna, Nasir El-Rufai. Idi ni pe lara awọn ti wọn sun mọ Buhari daadaa ko tilẹ too di Aarẹ ni, oun yii si wa lara awọn to n rin kiri Naijiria pe ki wọn dibo fun Buhari, yoo ṣe Naijiria daadaa. Ṣugbọn loju wọn yii naa ni Buhari ṣe n ba Naijiria jẹ pẹlu gbigba awọn Fulani laaye lati ko ogun ja wa nilẹ wa. Ṣugbọn pẹlu gbogbo aburu awọn Fulani onimaaluu, El-Rufai ko wi kinni kan, nigba to jẹ Fulani loun naa, to si nigbagbọ pe bi iya kan ba jẹ Fulani nibi kan, Fulani gbọdọ gbẹsan. Ṣugbọn nigba ti awọn araalu bẹrẹ si i le Fulani onimaaluu laduugbo wọn nitori aburu, El-Rufai jade, o ni ko yẹ ko ri bẹẹ, ibi to ba wu ọmọ Naijiria gbogbo lo le gbe, ko si ẹni to le le wọn jade, ko ba ofi mu rara. Ibi to ba wu Fulani lo le gbe, ta lo waa sọ pe ki wọn maa gbe ibi to wu wọn. Oun naa n sọrọ bii awọn alailarojinlẹ ẹgbẹ Arewa, awọn ti wọn ni bi wọn ba le Fulani nilẹ Yoruba, awọn naa yoo le Yoruba nilẹ Hausa. Njẹ ọmọ Yoruba kan huwa were, iwa ẹhanna, iwa ọmọ garawa ti awọn Fulani oni maaluu n hu nibi yii ni ilẹ tiwọn lọhun-un ri! O di ọjọ wo ti wọn mu Yoruba ni ilẹ Hausa pe o n dunbu eeyan, tabi pe o lọọ fi maaluu tirẹ jẹ oko oloko, o si pa oloko nitori iyẹn ni ko ma ṣe e. Bi eeyan ba waa n fi ohun to n ṣẹlẹ lọdọ wa nibi we awọn Yoruba ilẹ Hausa, ki i ṣe pe laakaye ti jinna si  onitọhun niyẹn. Fulani n paayan kiri, wọn n huwa ibajẹ buruku loriṣiiriṣii niluu oniluu, El-Rufai ni nibi to ba wu Fulani lo le gbe. Pẹlu iru ironu bayii, iru ọkunrin yii ko ni i ba Buhari sọ ododo, bẹẹ gomina ẹgbe APC ni, awọn ti ẹnu wọn tọrọ, to yẹ ki wọn le ba Buhari sọrọ niyẹn. Ṣugbọn Buhari ti ko awọn ẹlẹtan yi ara rẹ ka, boya ẹlẹtan si loun naa funra ẹ, nitori ẹgbẹ ẹyẹ ni ẹyẹ n wọ tọ, ohun toun naa ba n ṣe lawọn to ba n tẹle e yoo ṣe. El-Rufai, ko sẹni to sọ pe ki Fulani ma gbe ibi to ba wu u, ẹyin ni ki ẹ sọ fun awọn Fulani eeyan yin pe ki wọn huwa bii eeyan, ki wọn yee huwa bii ẹranko!

Ohun ti apa wọn ko ṣe ka Boko Haram niyẹn

Ẹ wo ọjọ ti a ti wa lẹnu ọrọ Boko Haram, ati awọn janduku Fulani nilẹ Hausa, ti wọn n pa awọn eeyan lojoojumọ, ti wọn si n ji awọn eeyan gbe, ti ijọba yii ko si le kapa wọn. Ki lo de ti ijọba yii ko kapa wọn? Apa ko le ka wọn, nitori Fulani ni wọn, ko si si ẹni ti wọn fẹẹ gbọrọ si lẹnu ju Fulani bii tiwọn lọ, iyẹn awọn Boko Haram. Kaka ki ijọba tiwa si doju ija kọ wọn, niṣe ni wọn n fọwọ pa wọn lori, ti wọn si n ba wọn ṣere, o tẹ wọn lọrun ki wọn maa gba owo, ki wọn si maa se bi wọn ti n ṣe yii, nigba to jẹ owo ijọba Naijiria ni wọn n fun wọn. Ẹ wo ohun to ṣẹlẹ lọsẹ to kọja, ọkan ninu awọn olori ẹlẹsin Islaam nilẹ Hausa, Sheikh Gumi, lọ si ọdọ awọn Boko Haram, awọn janduku to n pa gbogbo eeyan lẹkun jaye ninu igbo yii, o ni oun lọọ ba wọn sọrọ. Bi ẹ ba wo aworan tabi fidio iṣẹlẹ naa, ẹ oo ri i bi Gumi ṣe jokoo laarin awọn ọdaran ti ijọba Naijiria n wa lati ọjọ yii, laarin awọn olori Boko Haram ti wọn n ko waa ba wa. Bi ijọba Naijiria ba yi awọn eeyan naa po, ti wọn ko wọn lẹẹkan naa, dajudaju, ko ni i si ọrọ Boko Haram laarin wa fun igba pipẹ. Ati pe kin ni ijọba apapọ n lọọ ba janduku ati awọn afẹmiṣofo ṣepade si, nitori o daju pe lilọ ti wọn lọ  yii, Gumi ko ni i lọ bi ijọba apapọ ko ba fọwọ si i. Iru ipade wo lawọn Buhari n ba awọn Boko Haram yii ṣe. Ṣugbọn ipade naa aa yeeyan nigba ti Gumi jade, o ni ki ijọba apapọ lo owo sikiọriti to ti ya sọtọ, ko fi yanju ọrọ awọn Fulani yii. Bawo lo ṣe fẹẹ fi yanju ọrọ wọn, ko ko owo fun wọn naa ni. O si daju pe awọn Buhari yii yoo ko owo yii fun wọn o, bi wọn ba si ko o fawọn yẹn tan, wọn yoo fi ra ibọn tawọn ṣọja Naijiria ko ni, wọn yoo fi ra maṣin-gannu, wọn yoo si jokoo pa silẹ Hausa nibẹ, wọn yoo maa gbowo ori lọwọ awọn eeyan. Ṣe awọn Boko Haram yoo fi ilẹ yii silẹ ṣaa! A ti wọ gau!

Ki lo tun ku, ọrọ ti pesi jẹ o

Ọlọrun nikan lo le ṣalaye bi ọkan awọn ti wọn n ṣe ijọba Buhari yii ṣe n ronu o. Ọlọrun nikan lo mọ ọn, nitori bo ba jẹ ohun ti wọn n ṣe yii, ti a n foju ri yii ni, ko si daadaa kan ti yoo ti inu ijọba yii jade. Idi ni pe ironu wọn o daa ni! Ironu raurau! Ẹ wo ohun to ṣẹlẹ lọsẹ to kọja yii, Buhari le awọn olori ologun rẹ gbogbo lọ, ati olori ṣọja, ati olori Nefi ati olori ologun ofurufu. Inu gbogbo araalu si dun si ohun to ṣe. Ki i ṣe pe wọn n dunnu nitori pe wọn koriira awọn eeyan yii kọ, wọn n dunnu nitori pe awọn eeyan naa ko kun oju oṣuwọn lati igba ti wọn ti wa lẹnu iṣẹ yii, kaka ki ọrọ awọn Boko Haram, ọrọ awọn janduku, lọ silẹ tabi dinku, o n buru si i ni, o n le si i lojoojumọ ni, koda, titi di asiko yii, awọn agbegbe kan wa nilẹ Hausa to jẹ awọn janduku yii ni wọn n gba owoori nibẹ. Ohun to jẹ ki inu awọn eeyan dun nigba ti wọn yọ awọn olori ologun yii, ti wọn si fi awọn eeyan mi-in rọpo wọn niyẹn. Ṣugbọn ko too di pe inu awọn eeyan bẹrẹ si i dun ju, Buhari ge idunnu wọn kuru. Kia lo ti yan gbogbo awọn mẹrẹẹrin si ipo Amabasadọ, iyẹn ni pe awọn eeyan naa yoo lọọ jẹ aṣoju ijọba Naijiria lẹyin odi. Itumọ eleyii ni pe loju Buhari, awọn eeyan naa ṣe daadaa nidii iṣẹ ti wọn fi wọn si yii, debii pe o yẹ ki wọn maa jẹgbadun lọ titi ti wọn yoo fi ku ni. Awọn eeyan yii ko kọ iṣẹ aṣoju ijọba nibi kan ri, ni gbogbo aye wọn, ologun ni wọn, ohun ti wọn si ti ṣe fun bii ọdun marundinlogoji niyẹn. Awọn ti wọn kọ iṣẹ yii wa nilẹ o, awọn to jẹ ohun ti wọn n fi aye wọn ṣe ree. Buhari ko ri ninu awọn yii, awọn aloku ṣọja ti wọn ti ta tan, ti wọn ti ra tan, ti wọn si wa ninu awọn to ba nnkan jẹ lori lọrọ ifẹmiṣofo yii, awọn naa ni Buhari mu lati fi ṣe aṣoju ilẹ wa nilẹ okeere, lọjọ keji to yọ wọn nipo olori ologun. Bawo ni iru eleyii yoo ṣe mu ere wa, bawo ni iru eleyii yoo ṣe mu ilọsiwaju kankan ba Naijiria. Rara o, eleyii ko le mu ere wa, ko si le mu ilọsiwaju kan ba Naijiria, lara ifasẹyin tuntun ti ijọba Buhari mu waa ba wa ni.

Bẹẹ ki i ṣe pe awọn ọmọ Naijiria ni ko daa o

 

Ki i  ṣe pe awọn ọmọ Naijiria ni ko daa o, awọn ijọba alailero lori gbogbo ti a n ni lo n ko ifasẹyin ba wa, awọn naa ni wọn si n fa Naijiria sẹyin funra wọn. Ẹ wo ijọba tuntun ti wọn ṣẹṣẹ mu wọle nilẹ Amẹrika, ẹ wo iye ọmọ Naijiria ti wọn rọ sinu ijọba ọhun o. Ti a ba ti yọwọ awọn ọmọ Amẹrika nikan, ko tun si orilẹ-ede ti wọn jẹ alejo l’Amẹrika, ti awọn ọmọ ibẹ pọ ninu ijọba tuntun yii ju awọn ọmọ Naijiria lọ. Bẹẹ ni awọn Amẹrika yii ki i ṣe ojuṣaaju, ẹni ti wọn ba gbe si ibi iṣẹ kan mọ iṣẹ naa ni. Eyi ni pe wọn ko deede mu ọmọ Naijiria, wọn mọ pe wọn mọ ohun ti wọn n ṣe, wọn si ti dan wọn wo, wọn mọ pe wọn yoo ṣe iṣẹ awọn daadaa. Bi ẹ ba ri i daadaa, ẹ oo ri i pe ko si ọmọ Hausa ẹyọ kan ninu awọn ti wọn mu, Yoruba ati Ibo ni. Idi ni pe iwe ti Hausa ba ka nibi, wọn ko ka a lati mọ ẹkọ ti wọn kọ, tabi lati ni imọ, wọn ka a lati fi tu awọn ẹya to ku ni Naijiria jẹ ni. Eyi lo ṣe jẹ bi wọn ba ti jade, ipo nla ni wọn yoo gbe wọn si, ti wọn yoo si maa fi wọn ṣe olori ileeṣẹ ijọba. Ṣugbọn bi wọn ba gbe wọn depo naa tan, loju-ẹsẹ ni wọn yoo ba ileeṣẹ naa jẹ: bo jẹ ileeṣẹ to n jere ni, ko ni i jere mọ, bo jẹ ileeṣẹ to n ṣe daadaa tẹlẹ ni, ko ni i ṣe daadaa mọ, laipẹ lai jinna, wọn yoo lu ileeṣẹ naa ni gbanjo gbẹyin ni. Ohun to fa a ni pe awọn eeyan yii ko lẹkọọ tabi iriri awọn iṣẹ ti wọn n gbe fun wọn, wọn n fi wọn sipo yii nitori wọn jẹ ọmọ Hausa-Fulani ni. Ṣugbọn ko si eyi to kan wọn l’Amẹrika, ẹni ti wọn ba fi sipo kan kun oju oṣuwọn ni, wọn ko si fẹẹ mọ ibi to ti wa tabi iran to bi i. Bẹẹ ki i ṣe Amẹrika nikan ni wọn ti n ṣe eyi, gbogbo orilẹ-ede to ba fẹẹ nilaari ni. Afi ti Naijiria nikan, to jẹ oko ifasẹyin lawọn eeyan yii n mu wa lọ. Ọlọrun o, dide ko o waa gba agbara lọwọ wọn, nitori agbara ti o fun wọn yii, aburu ni wọn fi  n ṣe fun Naijiria, ati fun gbogbo aye.

Leave a Reply