Aderounmu Kazeem
Bi ilu Iru nipinlẹ Eko ṣe n dun yungba, ti gbogbo eeyan n dunnu, bi ọba ilu naa, Ọba Abdulwasiu Ọmọgbọlahan Lawal ṣe ṣayẹyẹ igbade ẹ lana-an, Aṣiwaju Bọla Tinubu ti ki i nilọ wi pe, afi ki o ko awọn eeyan ilu ẹ mọra, ki o baa le ṣaṣeyọri lori ipo ọhun.
Lara awọn eeyan nla to wa nibẹ lọjọ naa ni, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, Dokita Kadiri Ọbafẹmi Hamzat ti i ṣe igbakeji gomina ipinlẹ Eko, Ọọni Ile Ifẹ atawọn eeyan pataki mi-in.
Ninu ọrọ Bọla Tinubu lo ti ṣapejuwe kabiyesi naa gẹgẹ bii ọlọpọlọ pipe, ti oun si ri gẹgẹ bi ọmọ.
O ni, asiko niyi fawọn eeyan ilu naa lati gbaruku ti ẹni ti Ọlọrun yan fun wọn, ki ọba naa paapaa si fọgbọn ati iwa irẹlẹ ba awọn eeyan ẹ lo, ki o le ṣe aṣeyọri nla.
Ninu ọrọ Dọkita Hamzat, o rọ ọba alaye naa lati fọwọsowọ pọ pẹlu ijọba, ki o si tubọ mu irẹpọ gidi wa laarin awọn eeyan ilu ẹ.
Bakan naa lo ṣapejuwe Ọba Ọmọgbọlahan yii gẹgẹ bi oloye kikun, eyi to ti n fi eyi han bayii laarin oṣu mẹta pere to gori ipo ọhun.
Ninu ọrọ Kabiyesi Ọmọgbọlahan Lawal, ẹni ti i ṣe ọba kẹẹdogun to jẹ niluu Iru l’Ekoo yii, o dupẹ lọwọ Aṣiwaju Tinubu, ijọba ipinlẹ Eko atawọn ladelade to wa, bẹẹ lo ṣeleri pe asiko toun yii, igbega nla ati ilọsiwaju gidi ni yoo ba ilu Iru.