Ṣoworẹ atawọn ọdọ tun ṣewọde l’Abuja, wọn ni dandan ni ki Buhari lọ

Faith Adebọla

 Ọjọ Aje ti kaluku n gba ọna iṣẹ aje lọ lọjọ Mọnde, ṣugbọn niṣe lawọn ọdọ tinu n bi fi ọjọ Aje ọsẹ yii ṣe iwọde nla, wọn ya bo ọna to lọ si papakọ ofurufu Nnamdi Azikiwe, lolu-ilu ilẹ wa, wọn tun di ọna Shehu Musa Yar’Adua, wọn n pariwo pe awọn o fẹ Aarẹ Muhammadu Buhari mọ, pe ko kuro lori aleefa.

Ba a ṣe gbọ, wọn lawọn ọdọ naa dara pọ mọ ẹgbẹ ajafẹtọọ oniroyin ayelujara nni, Ọmọyẹle Ṣoworẹ, atawọn alatilẹyin rẹ, lati nnkan bii aago marun-un fẹẹrẹ ọjọ kọkanlelogun, oṣu yii, lawọn ọdọ naa ti kora jọ si oju ọna marosẹ ọhun, wọn si n dana sun taya lori titi naa, bẹẹ ni wọn n kọrin ẹhonu loriṣiiriṣii, ti wọn n sọ pe ijọba Buhari ti su awọn, ki Buhari maa lọ lawọn fẹ.

Nigba ti yoo fi di aago mẹjọ si mẹsan-an ọjọ naa, awọn ọdọ ọhun ti di ọna naa pa bamu, ko si ṣee ṣe fun ọkọ eyikeyii lati kọja, wọn niṣe lawọn ọdọ naa n fibinu da awọn eeyan to n kanju lati lọọ wọ baaluu ni papakọ ofurufu pada.

Lara orin ẹhonu ti wọn mu bọnu ni: “Ṣe demokiresi leyi ṣa, ṣe demọkiresi leyi ṣa, ijọba tawọn eeyan n ku bii eṣinṣin, ṣe demokiresi leyi ṣa. ‘‘Wọn tun fẹsun kan Buhari pe asiko rẹ ni epo bẹntiroolu lọ soke lati naira mẹtadinlaaadọrun fun jala kan lọ si ọgọjọ naira (N160), bẹẹ ni gbogbo ounjẹ di ọwọnogo, gbogbo ọrọ-aje lo dẹnu kọlẹ, wọn lawọn ko le fara mọ-ọn mọ, ki Buhari kẹru ẹ kuro nile ijọba lawọn fẹ.

Bakan naa ni wọn gbe awọn akọle dani, gbolohun kan to si wa lara awọn akọle naa ni pe ki Buhari waa maa lọ.

Lara nnkan tawọn ọdọ naa lawọn n fẹ ni ki ijọba wa ojuutu si eto aabo to mẹhẹ yii, ki iṣakoso rere wa, ki wọn fopin si iwa jẹgudujẹra, jijaye alabata, ati pe kijọba da ipinnu wọn lati fofin de ikanni ibaniṣọrọ tuita pada.

Ṣaaju lori ikanni ayelujara rẹ ni Ọmọyẹle Ṣoworẹ ti kede pe iwọde ta ko Buhari ati iṣejọba rẹ maa waye lọjọ Aje, Mọnde yii, ati pe lọtẹ yii, oorekoore lawọn yoo maa ṣe iwọde ati ifẹhonu han naa lọ titi ti Buhari yoo fi kuro lori aleefa.

Lori ikanni fesibuuku ati tuita ọhun lawọn eeyan kari aye ti n sọrọ nipa iwọde to n lọ lọwọ yii, ọpọ lo si n gboriyin fun awọn ọdọ naa.

A gbọ pe awọn agbofinro duro wamuwamu sitosi awọn ọdọ to n fẹhonu han yii, ṣugbọn wọn ko di wọn lọwọ, bẹẹ ni wọn ko ti i kọ lu wọn, lasiko ti a n ko iroyin yii jọ lọwọ.

Leave a Reply