Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ọwọ awọn ọlọpaa Agbado, nipinlẹ Ogun, ti tẹ baba agbalagba ẹni ọdun mẹrinlelọgọta yii (64), Alagba Ayọtunde Taiwo, ẹni ti wọn lo fipa ba ọmọ ọdun meji pere lo pọ lọjọ Iṣẹgun,Tusidee, ọjọ keje, oṣu kẹsan-an yii, l’Agbado.
Gẹgẹ bi iya ọmọdebinrin naa ṣe ṣalaye fawọn ọlọpaa ni nnkan bii aago mọkanla aarọ ọjọ naa, o ni oun kan deede ri i pe ọmọ oun ko le rin daadaa ni, niṣe lo n gadi rin. O loun sun mọ ọn, oun yẹ ara rẹ wo, nigba naa loun si ri ẹjẹ loju ara rẹ.
Iya ọmọ naa ni oun beere lọwọ ọmọde yii pe ki lo ṣẹlẹ si i, o si nawọ si ile to wa lọọọkan ile awọn, loun ba mu un gba ibẹ lọ.
O ni nigba tawọn debẹ, niṣe lawọn ba baba agba yii, Ayọtunde Taiwo, to n fọ ṣokoto penpe tawọn ọkunrin maa n wọ tẹlẹ (boxer), eyi ti ẹjẹ wa lara rẹ, eyi si fi han pe oun lo fipa ṣe ere buruku fun ọmọ kekere ọhun.
Ohun to mu iya ọmọ gba teṣan lọ ree, ti CSP Kẹhinde Kuranga, DPO teṣan Agbado, fi ko awọn ikọ rẹ lẹyin, ti wọn si lọọ mu baba agba yii.
Ọmọ kekere to ṣe yankanyankan naa ti wa labẹ itọju lọsibitu, wọn si ti taari baba naa si ẹka to n gbọ ẹsun bii eyi l’Ọta, nibi ti wọn yoo ti pe Ayọtunde Taiwo lẹjọ.