Monisọla Saka
Asiko yii ki i ṣe eyi to dara rara fun ọkan ni awọn gbajumọ arẹwa oṣerebinrin ilẹ wa nni, Fathia Balogun. Eyi ko ṣẹyin bi ọmọbinrin naa ṣe padanu baba to bi i lọmọ lẹni ọgọrin ọdun.
Lọsan-an ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni arẹwa oṣere yii kede iku baba naa.
Fathia ni, “Pẹlu ọkan to wuwo, o ba mi lọkan jẹ lati sọ pe o daarọ fun baba mi ọwọn. Mo padanu baba mi lonii lẹni ọgọrin dun. Ohun to dun mọ mi ninu ju ni pe ko gbe ẹnikẹni sin ninu wa. Mo si dupẹ lọwọ Ọlọrun pe a ko maa nawo anadanu lati fi wo o lori aarẹ. Ṣugbọn o wu wa ki baba ṣe diẹ si i laarin wa. Inu mi bajẹ, mo ti sunkun sunkun, ti mo si n ronu bi wọn ṣe jẹ eeyan daadaa si wa to. Irinajo to kun fun oriṣiiriṣii nnkan ni irinajo awa pẹlu wọn nigba ti wọn wa laye.
Ẹ jọwọ, ẹ ma binu si mi ti mi o ba gbe ipe yin, mo ṣi n ṣọfọ baba mi”.
Bo tilẹ jẹ pe oṣere yii ko sọ nnkan to ṣokunfa iku baba rẹ ati ibi ti baba naa ku si, ọpọlọpọ awọn ẹgbẹ rẹ nidii iṣẹ tiata, to fi mọ awọn ololufẹ rẹ lori ayelujara, ni wọn ti n fi ọrọ tutu ati adura ba ọmọlooku daro ipapoda baba rẹ.
Lara awọn gbajumọ oṣere to ti ranṣẹ ibanikẹdun si Fathia pẹlu ọpọlọpọ adura ati ọrọ imulọkanle ni Iyabọ Ojo, Jumọkẹ George, Kunle Afod, Ayọ Ọlaiya, Bukọla Adeẹyọ, Chioma Akpotha, Kẹmi Korede, Funkẹ Ẹtti, Jaye Kuti, Dayọ Amusa, Yinka Quadri ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Gbogbo wọn ni wọn ṣadura fun un pe ki Ọlọrun tẹ baba si afẹfẹ rere, ki o si duro ti awọn mọlẹbi rẹ.