Ẹgbẹ oniṣẹṣe kilọ fawọn ọdọ: Itanjẹ lasan ni, ko si nnkan to n jẹ oogun-owo ninu Ifa

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Pẹlu bi ọpọ awọn ọdọ orileede yii ṣe n fi ẹmi ara wọn wewu lojoojumọ latari owo ojiji ti wọn n wa, agbarijọpọ ẹgbẹ awọn oniṣẹṣe, Traditional Religion Worshipers Association (TRWASO) ti sọ gbangba pe ko si nnkan to n jẹ oogun-owo ṣiṣe ninu Ifa, itanjẹ lasan ni.

TRWASO sọ pe ṣiṣe oogun-owo jẹ ajeji si aṣa ati ẹsin ibilẹ nilẹ Yoruba, ko si si ẹsẹ Ifa kankan to fara mọ iru nnkan bẹẹ.

Nibi ayẹyẹ ibura fun awọn oloye ẹgbẹ naa nipinlẹ Ọṣun, eleyii to waye niluu Oṣogbo, ni Aarẹ tuntun ti wọn yan fun saa keji, Dokita Oluṣeyi Atanda, ti kilọ fawọn ọdọ lati ṣọra fun ẹgbẹkẹgbẹ to n ti wọn lati ṣiwa-hu bayii.

Atanda ṣalaye pe ojukokoro, ẹgbẹ buburu ati ẹsin ajeji lo n fa a ti ọpọ awọn ọdọ fi nigbagbọ pe nnkan to n jẹ oogun-owo wa.

O ke si awọn agbofinro lati ri i daju pe wọn n wọ ẹnikẹni ti ajere iwa ipaniṣowo ba ṣi mọ lori lọ sile-ẹjọ, lati le wagboo dẹkun fun awọn ti wọn ba tun n gbero iru ẹ.

Atanda parọwa si awọn ijọba lati faaye gba awọn afọbajẹ lati ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ lori iyansipo awọn ọba, o ni ipo ibilẹ ni ipo ọba, ọmọọba to ba si mọ pe oun ko ṣetan lati bọwọ fun aṣa ati iṣẹṣe ko gbọdọ sun mọ ipo naa rara.

O ni ẹgbẹ awọn Oniṣẹṣe ko ni i dẹkun gbigbogun ti awọn ọba ti wọn n ṣe nnkan to lodi si aṣa ati iṣẹṣe ti wọn gbe lọwọ, nitori itiju nla ni wọn jẹ fun iran Yoruba.

Bakan naa lo tun ke si awọn ijọba lati ṣamojuto awọn ibudo aṣa to wa kaakiri agbegbe wọn, nitori ohun kan pataki to le maa mu obitibiti owo wọle labẹnu funjọba ni.

Ninu ọrọ Alaga igbimọ majẹ-o-bajẹ ẹgbẹ TRWASO, Oloye Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn, o ke si awọn oloye tuntun naa lati ma ṣe kaaarẹ ninu igbesẹ wọn lati mu idagbasoke ba ẹsin Iṣẹṣe nipinlẹ Ọṣun, ati kaakiri orileede yii.

Leave a Reply