Eyi ni bi Sẹnetọ Olurẹmi Tinubu ṣe gba mi lọwọ awọn oniroyin to fẹẹ maa fi mi pawo – Adeleke

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ti ṣapejuwe aya aarẹ orileede yii, Sẹnetọ Rẹmi Tinubu, gẹgẹ bii ẹni to ko gbogbo eeyan mọra, ti ki i si i ṣe ẹlẹyamẹya.

Lasiko ti Rẹmi Tinubu n ṣepade pẹlu awọn lọbalọba nipinlẹ Ọṣun, ninu ilegbee gomina ni Adeleke ti ṣalaye pe ohun manigbagbe ni aya aarẹ ṣe f’oun lasiko ti awọn jọ wa nileegbimọ aṣofin agba.

O ni igba kan wa ti oun n sun lasiko ti ijiroro n lọ lọwọ ni ijokoo ile awọn aṣofin, bi awọn oniroyin si ṣe ri i ni wọn ya fọto, ti wọn si bẹrẹ si i fi dunkooko mọ oun.

‘’Wọn fẹẹ fi ọrọ yẹn ba mi lorukọ jẹ, mo ṣalaye fun wọn pe ṣe lo rẹ mi, nitori iṣẹ to pọ la maa n ṣe nileegbimọ aṣofin agba, ọpọ igba ni a ki i raaye sun titi di aago mẹrin idaji maa fi lu.

‘’Gbogbo alaye mi ni ko ye wọn, wọn ko fẹẹ gbọ nnkan ti mo n sọ, emi gan-an si ti fẹẹ maa bẹru lati fun wọn lowo ti wọn n beere.

‘’Lọjọ kan, mo sare lọọ ba Mama (Rẹmi Tinubu)m lasiko ti wọn fẹẹ maa lọ si Eko, mo sọ fun wọn pe mo n sun, awọn oniroyin si ri mi, o si da bii ẹni pe wọn fẹẹ fi kinni naa gba owo lọwọ mi ni.

‘’Bi mo ṣe sọrọ tan ni Mama sọ pe, ‘Ma da wọn lohun, jẹ ki wọn lọọ kọ nnkan ti wọn ba fẹẹ kọ, sọ fun wọn pe eeyan ni ọ, nitori wọn ti ṣe bẹẹ fun emi naa ri’

”Mo ṣe bi wọn ṣe sọ pe ki n ṣe, mo si bọ lọwọ obitibiti owo ti wọn iba gba lọwọ mi. Ọpọlọpọ igba la maa n lọọ fi ọrọ lọ wọn nitori ọgbọn ati iriri ti wọn ni’’

 

Leave a Reply