Ẹwọn n run nimu ọkunrin to n ṣe piọ wọta yii o, inu kanga lo ti n pọn’mi to n rọ sinu ọra

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti tẹ ọkunrin ẹni aadọta ọdun kan, Ọgbẹni Jamiyu Adewọle, pẹlu ẹsun pe omi inu kanga kan to wa ninu ọgba ibi to ti n ṣe piọ wọta lo n rọ sinu ọra to n ta fawọn araalu laduugbo 132 KVA, Omisanjana, Ado-Ekiti.

Ọkunrin yii to jẹ gbaju-gbaja olomi inu ọra ni Ado-Ekiti, lawọn ọlọpaa sọ sinu ọkọ, wọn ti wọn si kọju rẹ si ọna olu ileeṣẹ wọn ni kutukutu aarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu yii.

ALAROYE gbọ pe ileeṣẹ olomi inu ọra naa n ṣiṣe lai gba iwe aṣẹ to daju latọdọ ìjọba ipinlẹ Ekiti, eyi ti wọn sọ pe o le fa ajakalẹ arun niluu naa.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe ọdaran naa ti wa lakata awọn lọwọlọwọ, tawọn si ti n fi ọrọ wa a lẹnu wo. O fi kun un pe awọn yoo gbe e lọ sile-ẹjọ ni kete tawọn ba pari iwadii lori ọrọ naa.

O ṣalaye pe afurasi ọdaran yii n fa omi lati inu kanga kan ọlọjọ pipẹ to wa ni ayika ileeṣẹ naa, to si n rọ ọ sinu ọra ati inu ile, kanga yii ni alukoro ṣalaye pe ko dara to fun ilera awọn eeyan awujọ.

Ni nnkan bii ọṣẹ meji sẹyin ni ileeṣẹ to n mojuto eto ayika nipinlẹ Ekiti ti kọkọ ti ileeṣẹ naa pa, pẹlu ẹsun pe ibi to ti n fa omi to n lo ninu ọgba naa ko dara to. Wọn ni kanga ti wọn ti fi silẹ lati ọjọ to ti pẹ, to si wa ninu ile akọku ni adugbo ti ileeṣẹ naa wa ni wọn n lo.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Ọga agba ileeṣẹ eto ayika nipinlẹ Ekiti to dari awọn oṣiṣẹ yooku lọ lati ti ileeṣẹ naa pa, Ọgbẹni Sunday Adebayọ, ṣalaye pe iwa aibikita ti wọn n hu nibẹ le fa ajakalẹ arun. O ni ayika ti omi ti wọn n lo lati ṣiṣe yii wa ko dara to.

Leave a Reply