A maa bẹrẹ si i ṣe ayẹwo ọpọlọ fawọn arufin oju popo ka a too pe wọn lẹjọ – Ijọba Eko

Monisọla Saka

Ijọba ipinlẹ Eko ti ni gbogbo arufin ojupopo ti ọwọ ba ti tẹ lati isinyii lọ, paapaa ju lọ, awọn to n wa ọkọ ni opopo ti ki i ṣe ti wọn, ti wọn n pe ni One-way, yoo kọkọ lọọ ṣe ayẹwo ọpọlọ, lati le mọ boya wọn ko ni ipenija ọpọlọ, lẹyin naa lawọn yoo foju wọn bale-ẹjọ.

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni Kọmiṣanna fun igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Eko, Oluwaṣeun Oṣiyẹmi, sọrọ naa di mimọ lasiko ti wọn n jiyin iṣẹ ti wọn ti ṣe ati akitiyan ileeṣẹ naa lati ọjọ yii wa labẹ iṣejọba Gomina Babajide Sanwo-Olu, to waye ni Alausa, Ikẹja, nipinlẹ Eko.

Oṣiyẹmi ni ọrọ ki mọto maa dojukọ ibi tawọn ọkọ yooku kẹyin si, ki wọn si maa gba ọna ti ki i ṣe tiwọn jẹ ohun to ba ni lọkan jẹ, ati pe ijọba gbọdọ fopin si i.

“Lati akoko yii lọ, ayẹwo ọpọlọ la oo kọkọ ni ki arufin tọwọ ba ba lọọ ṣe na, lẹyin naa ni ijọba ipinlẹ Eko yoo pe e lẹjọ lori pe o ta ko ofin irinna oju popo”.

Bakan naa ni Oṣiyẹmi fi awọn nọmba ibanisọrọ yii sita,  09020009000 ati 09020004000, fawọn eeyan lati pe wọn, ti wọn ba kẹẹfin awọn ayederu oṣiṣẹ ileeṣẹ to n mojuto irinna ọkọ oju popo nipinlẹ Eko.

O ni ojoojumọ ni wọn n pọ si laarin ilu, ọwọ si gbọdọ ba wọn, ki wọn le fi wọn jofin.

 

Leave a Reply