Ijọba Kwara ti bo awọn ẹran maaluu to jẹ majele tawọn alapata kan fẹẹ maa ta faraalu mọlẹ 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Wọn ni ohun ti a o ba fẹ ko bajẹ, oju ni a a mu to o. Eyi lo fa a ti ijọba ipinlẹ Kwara, ṣe lọọ ko gbogbo awọn ẹran maaluu ti wọn ni majele pa ni Ọja Mandate, to wa ni agbegbe Adéwọlé, niluu Ilọrin, tawọn alapata kan n ta faraalu, tijọba si lọọ da gbogbo ẹ sinu koto, ti wọn bo o mọlẹ lati dena ajakalẹ arun nipinlẹ naa.

Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin ileeṣẹ to n ri si ọrọ eto ọgbin ati idagbasoke igberiko nipinlẹ Kwara, Ọladipọ Temple Oluṣọla, fi sita lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, to tẹ ALAROYE lọwọ lo ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ pe ijọba ti lọọ ko gbogbo awọn ẹran maaluu ti wọn lo jẹ majele tawọn alapata si n ta faraalu ninu ọja Mandate, niluu Ilọrin, ti wọn si ti bo gbogbo ẹ mọlẹ.

Bakan naa, ni wọn gbe fọnran fidio to ṣafihan ibi ti ijọba ti gbẹ koto giriwo, ti wọn si n da awọn ẹran maaluu sinu ẹ, lẹyin naa ni wọn da erupẹ bo o mọlẹ.

Oluṣọla ni iwadii fidi ẹ mulẹ pe awọn maaluu ọhun jẹ majele mọ koriko lasiko ti wọn fi wọn jẹko lọ ninu ọgba ileewe College of Arabic and Islamic legal Studies, to wa lagbegbe Mandate, niluu Ilọrin.

Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Abamẹta, Satide, ogunjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, lawọn maaluu to le ni ogoji to jẹ ti awọn kan ti wọn n ta maaluu ku lojiji, latari majele ti wọn jẹ.

ALAROYE gbọ pe ni kete tawọn maaluu ọhun n ku ni awọn alapata to n ta a ti n du wọn lọrun, ti wọn si n gbe ẹran naa lọ sinu ọja lati lọọ ta a faraalu.

Leave a Reply