Tinubu tun fẹẹ yawo lọwọ Banki Agbaye

Faith Adebọla

Minisita fun eto iṣuna-owo nilẹ wa, Ọgbẹni Wale Ẹdun, ni gbogbo eto ti pari, ajọsọ ati adehun si ti fori mẹyin laarin orileede Naijiria ati Banki Agbaye, lati ya owo ti iye rẹ jẹ biliọnu meji aabọ dọla ($2.25b).

Wale Ẹdun sọ eyi di mimọ lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ nibi ipade pataki kan ti ajọ International Monetary Fund (IMF), ṣe, eyi to waye lọjọ Abamẹta, Satide, ogunjọ, oṣu Kẹrin, ọdun yii, niluu Washington DC, ti i ṣe olu-ilu orileede Amẹrika.

O ni ẹyawo yii, to fẹrẹ da bii ounjẹ ọfẹ, ọdun mẹwaa ni Naijiria yoo fi lo o lai san nnkan kan lori ẹ, lẹyin naa lawọn yoo bẹrẹ sisan-pada rẹ laarin ọgbọn ọdun, pẹlu ele ori owo ti ko ju ida kan ninu ọgọrun-un lọ, leyi to tumọ si pe aropọ ogoji ọdun ni wọn yoo fi lo owo naa.

Bakan naa ni Wale Ẹdun tun sọ pe banki to n ṣiṣẹ fun idagbasoke ilẹ Adulawọ kan, Africa Development Bank (ADB) ti ṣeleri lati pese ẹyawo ti ele ori rẹ ko ni i gara ju fun Naijiria, bẹẹ lo ni ajọsọ ọrọ ti n lọ lọwọ pẹlu awọn olokoowo agbaye kan lati waa da iṣẹ silẹ ni orileede wa. O lawọn maa lo ẹyawo yii lati pese nnkan amayedẹrun ti yoo tubọ fa oju awọn olokoowo naa mọra, ki wọn le gbe iṣẹ wọn wa.

Leave a Reply