Aarẹ Tinubu n lọ s’orileede Netherlands, yoo gba’bẹ sọda si Saudi

Faith Adebọla

Bi ilẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii ṣe n mọ, Olori orileede wa, Bọla Ahmed Tinubu, yoo ti palẹ ẹru rẹ mọ, ti yoo si tẹkọ leti lọ sorileede Netherlands, fun abẹwo pataki kan.

Oludamọran pataki Aarẹ lori eto iroyin, Ọgbẹni Ajuri Ngelale, lo sọrọ yii di mimọ ninu atẹjade kan laṣaalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹrin yii.

O ni Olori ijọba Netherlands, Ọgbẹni Mark Rutte, lo kọwe si Tinubu pe oun fẹẹ gba a lalejo.

Wọn ni Tinubu maa lo anfaani abẹwo naa lati fikun lukun pẹlu Rutte, ti yoo si tun ṣepade pẹlu Ọba ilu ọhun, William Alexander ati Ayaba Maxima, ti i ṣe aṣoju Akọwe agba ajọ United Nations lori eto iṣuna-owo ati idagbasoke.

Bakan naa ni Aarẹ Tinubu yoo kopa ninu apero awọn olokoowo kan, Nigeria-Dutch Business and Investment Forum.

Lẹyin ọjọ diẹ, Tinubu yoo kọja si orileede Saudi Arabia, fun apero ọrọ-aje agbaye, World Economic Forum, ti wọn yoo ṣe ni ọjọ kejidinlọgbọn si ikọkandinlọgbọn, oṣu Kẹrin yii.

Ngelale ni awọn minisita kan atawọn amugbalẹgbẹẹ Aarẹ yoo kọwọọrin pẹlu rẹ lọ irinajo yii, yoo si gba a to ọsẹ kan aabọ ko too de pada.

Leave a Reply