Irọ lawọn ọlọpaa n pa, a o dana sun-unyan mọle ni Gaa Wakili, awọn ni wọn kọkọ yinbọn mọ wa – OPC

Faith Adebọla, Eko

Lori awọn ẹsun oriṣiiriṣii tileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ fi kan ẹgbẹ Odua Peoples Congress, OPC ti wọn lọọ mu olori Fulani darandaran kan, Iskilu Wakili, lọjọ Aiku, Sannde, to kọja yii, tileeṣẹ ọlọpaa si lawọn ti tori ẹ sọ ọmọ OPC mẹta satimọle, ẹgbẹ naa ti sọ pe ki i ṣe bọrọ ṣe ri nileeṣẹ ọlọpaa sọ.

Akọwe iroyin fun Iba Gani Adams, Ọgbẹni Kẹhinde Aderẹmi, sọ f’ALAROYE pe nigba tawọn ọmọ OPC de Gaa ti Wakili atawọn ọmọọṣẹ rẹpẹtẹ n gbe, niṣe lawọn Fulani naa gbeja ko wọn, wọn ni ki wọn ma bọọlẹ ninu mọto rara. Ki wọn too mọ ohun to n ṣẹlẹ, o lawọn Fulani ti n yinbọn, lawọn ọmọ OPC naa si fibọn fesi pada, bẹẹ lawọn n ṣọ Wakili ti wọn tori ẹ wa ko maa lọọ gbọna ẹyin sa lọ.

Kẹhinde ni nibi tibọn ti n rọjo yii ni obinrin tawọn ọlọpaa sọ pe wọn dana sun mọle ti fara kaaṣa, “ibọn lo pa a, ki i ṣe pe wọn dana sun un. Ko si sẹni to le sọ pato boya ibọn ti OPC lo ba a tabi tawọn Fulani, tori awọn mejeeji jọọ faya ara wọn ni.”

“Ọpọ ọrọ ti ki i ṣe ootọ lo wa ninu atẹjade tileeṣẹ ọlọpaa kọ nipa iṣẹlẹ yẹn. Awọn ọlọpaa o de’bẹ, wọn o si nibẹ nigba tiṣẹlẹ naa waye, bawo ni wọn ṣe le sọrọ bii ẹni pe niṣoju wọn koro ni nnkan naa ṣẹlẹ.”

O ni nigba tawọn Fulani naa ri i pe awọn o le rọwọ mu, niṣe ni wọn bẹrẹ si i sa lọ, Wakili naa si ti wa laarin wọn, toun naa ti kan lugbẹ, kawọn ọmọ OPC ti wọn ti da a mọ tẹlẹ too gba fi ya a, ti wọn si ri i mu, ṣugbọn ọpọ awọn ẹmẹwa ẹ ni wọn sa lọ.

Kẹhinde tun ṣalaye pe ọmọ OPC mẹrin lawọn ọlọpaa mu satimọle nigba tawọn gbe Wakili de olu-ileeṣẹ ọlọpaa n’Iyaganku, n’Ibadan, o ni mẹta tawọn ọlọpaa sọ yẹn ki i ṣe ootọ, o loun o fẹẹ darukọ awọn ọmọ OPC naa tori iṣẹ iwadii to n lọ lọwọ, ati fun aabo wọn.

O lawọn agbaagba Yoruba ti sọrọ lori iṣẹlẹ yii, wọn si gboṣuba fun iṣapa ti OPC ṣe, wọn si bẹnu atẹ lu bawọn ọlọpaa ṣe kọ lati lọọ mu Iskilu Wakili, ti wọn tun waa mu awọn to mu Wakili satimọle. Lara awọn to sọrọ lori iṣẹlẹ yii ni Ọgbẹni Yinka Odumakin, agbẹnusọ ẹgbẹ Afẹnifẹre, atawọn mi-in.

Ni ti awọn ọmọ OPC ti wọn mu, o lawọn lọọya OPC ti bẹrẹ iṣẹ lori ẹ, wọn si ti bẹrẹ igbesẹ lati gba wọn silẹ lahaamọ ọlọpaa.

 

Leave a Reply