Lẹyin tawọn OPC lọ tan, eeyan mẹrin lawọn Fulani tun ṣa pa l’Abule Idiyan, n’Ibarapa

Akọwe iroyin fun Iba Gani Adams, Ọgbẹni Kẹhinde Aderẹmi, ṣalaye f’ALAROYE ni Mọnde, ọjọ Aje ọsẹ yii pe awọn o ridii to fi yẹ ki wọn fawọn ọmọ ẹgbẹ OPC satimọle, o ni nnkan to mu ki wọn ṣe bẹẹ ni pe awọn ọlọpaa ti ri i pe ogo to yẹ kileeṣẹ ọlọpaa gba lo jẹ pe awọn OPC lo gba a bayii, tori adehun to wa laarin awọn tẹlẹ ni pe awọn ọlọpaa ati Amọtẹkun ati OPC jọ maa ṣiṣẹ nifọwọsowọpọ ni lati mu Wakili, ṣugbọn lẹyin adehun ni awọn ọlọpaa bẹrẹ si i tadi mẹyin, wọn si kọ lati gbe igbesẹ.

Ni ti bi wọn ṣe ni ara Wakili o ya, pe oju n dun un, o ni niṣe lọkunrin naa pirọrọ, o lo dibọn ni, “ẹni to jẹ pe kanmọ kanmọ lo n sa lọ ninu papa ka too mu un, to waa denu mọto to loju n dun oun, oun o riran, ṣe ẹni ti o riran le sare ninu igbo.

Kẹhinde tun fidi ẹ mulẹ pe eeyan mẹrin lawọn Fulani tun lọọ pa loru mọju ọjọ Aje, Mọnde yii, lẹyin tawọn lọ tan. Abule Idiyan, to wa lọna oko kan laarin ilu Ayetẹ si Igangan leyi ti waye.  ALAROYE pe awọn eeyan kan niluu Ayetẹ, ọkunrin ti ko fẹ ka darukọ rẹ naa sọ pe loootọ ni iṣẹlẹ naa ati pe iyawo ọrẹ oun wa ninu awọn ti wọn pa yii. A gbọ pe oru ni wọn lọọ ka awọn eeyan mọ abule yii, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn, bi wọn ti n yinbọn lu awọn eeyan ni wọn tun n ṣa wọn ladaa. Nigba ti oloju yoo si fi ṣẹ ẹ, eeyan mẹrin lawọn Fulani naa ti tun pa.  Ohun ta a gbọ ni pe wọn ni wọn fẹẹ gbẹsan mimu ti wọn mu olori wọn ni, ṣugbọn awọn OPC ni awọn maa ṣẹgun wọn, gbogbo ohun to ba gba si lawọn maa fun un.

Ni ti bileeṣẹ ọlọpaa ṣe ni kawọn eeyan ti wọn ba lẹsun lodi si Wakili jade wa sọ, o lawọn eeyan o ti i jade, o si le ma rọrun fun wọn lati jade, pẹlu bo ṣe jẹ pe awọn to fẹẹ ran ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ ni wọn n gbe sọ satimọle yii, ṣugbọn awọn OPC gẹgẹ bii ẹgbẹ kan ti n ṣakojọpọ oriṣiiriṣii iwa laabi ati ifẹmiṣofo, biba oko oloko jẹ to waye latọwọ Wakili ati awọn ẹmẹwa ẹ to ko tira lagbegbe naa.

Titi di ba a ṣe n sọ yii, Kẹhinde ni awọn ọba alaye ilu Ayetẹ tabi ti Igangan ko ti i sọrọ lori iṣẹlẹ yii, bẹẹ ni wọn o ti i kan si ẹgbẹ OPC nipa aṣeyọri ọhun, ṣugbọn gẹgẹ bo ṣe wi, igbesẹ ṣi n tẹsiwaju lati ro awọn ọmọ OPC lagbara, ati lati ṣẹgun awọn ọbayejẹ Fulani darandaran ti wọn n yọ awọn agbẹ ataraalu lẹnu lagbegbe naa. O ni isapa OPC yii ko ni i mọ si agbegbe Ibarapa nikan, ṣugbọn kaakiri origun mẹrẹẹrin ilẹ Yoruba ni.

Leave a Reply