Awa Fulani  ti ṣetan lati ya kuro lara Naijiria ni kiakia- Miyetti Allah

Faith Adebọla

 

Ọrọ yiya kuro lara Naijiria ko mọ lọdọ ẹya Yoruba ati Ibo nikan o, awọn Fulani naa ti kede pe awọn fẹẹ ya kuro lara Naijiria, koda wọn lo wu awọn lati da duro ju bo ṣe wu awọn ẹya to ku lọ.

Akọwe agba ẹgbẹ awọn Fulani darandaran, Miyetti Allah Kautal Hore, Alaaji Alhassan Saleh, sọ pe awọn ẹya Fulani ti gbaradi, awọn si ti wa ni imuratan lati ya kuro lara orileede yii, awọn si le ṣe bẹẹ ṣaaju awọn ẹya to ku paapaa.

O ni iṣọkusọ ọrọ ni bawọn eeyan ṣe n di ẹbi aabo to mẹhẹ yii ru awọn Fulani darandaran bii ẹni pe awọn ni wọn o jẹ komi alaafia orileede yii toro, o ni awọn Fulani kọ ni iṣoro ti Naijiria ni.

“Meloo lawa Fulani to ba di ọrọ iṣoro Naijiria, meloo ni wa gan-an na, ṣe awọn Fulani lo n gbọn koto owo Naijiria gbẹ ni? Ṣe awọn Fulani lo n lu jibiti, ti wọn n ṣe owo ilu baṣubaṣu ni? Ipalara wo ni Fulani ṣe forileede yii? Ṣe a le fi wera pẹlu iwa ọdaran tawọn ọmọ ‘Yahoo’ ti wọn n lu jibiti ori atẹ ayelujara n ṣe ni, abi o dọgba pẹlu ti awọn ajinigbe, awọn oloṣelu onijẹkujẹ, awọn agbebọn ti wọn ṣakoso, awọn alarinkiri bii iru gomina ipinlẹ Benue yẹn (Samuel Orthom). Ṣe ẹ ro pe ti ko ba si owo epo rọbi, ṣe gbogbo nnkan wọnyi maa maa ṣẹlẹ ni, ṣe ilu aa ri bo ṣe ri yii ni?

“Lonii oloni yii, ti wọn ba lo ya, a ti ṣetan, ẹ jẹ ki wọn pin orileede, ki wọn tete pin in, ki wọn ma duro di ọla. O wu wa, a si ti mura tan ju gbogbo ẹya to ku lọ. O ti ya wa, ẹ jẹ ki wọn pin orileede yii, awa o ni epo rọbi, ẹ fi wa silẹ, ẹ jẹ ka ku.”

Bayii ni Saleh ṣe sọrọ nigba tawọn oniroyin bi i lere ọrọ nipa Naijiria lọjọ Ẹti, Furaidee yii.

Leave a Reply