‘A ko fara mọ Orilẹ-ede Yoruba ni tiwa, iṣọkan Naijiria la fẹ’

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Bi awọn ẹgbẹ ti wọn n ja fun idasilẹ Orilẹ-ede Yoruba ṣe n sọ tiwọn ni ẹgbẹ kan, bẹẹ ni awọn ẹgbẹ kan ti wọn n pe ni ‘Yoruba Appraisal Forum’(YAF) naa ti dide bayii ti wọn ni bo tilẹ jẹ pe Yoruba lawọn, awọn ko fẹ ki Naijiria pin. Wọn ni ki Yoruba maa jẹ ọmọ Naijiria lọ lawọn fẹ ni tawọn.

Iwọde lawọn ọmọ ẹgbẹ YAF fi fero ọkan wọn han l’Abẹokuta lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹjọ, oṣu kẹfa, ọdun 2021 yii. Gbọngan Iṣẹmabaye Centinary to kọju si aafin Alake ilẹ Ẹgba ni wọn duro si pẹlu akọle oriṣiiriṣii ti wọn fi n kede iṣọkan Naijiria lọwọ.

Alakooso ẹgbẹ YAF jake-jado Naijiria, Ọgbẹni Adeshina Animashaun, ṣalaye fawọn akọroyin pe niṣe lo yẹ kawọn oloṣelu dide si ọrọ yii, ki wọn koju awọn to n fẹ ki Naijiria pin si wẹwẹ, ki wọn da wọn lẹkọọ pe ninu ka wa papọ ni alaafia ati ilọsiwaju wa.

Ẹgbẹ yii ni kawọn eeyan ilẹ Yoruba ma da awọn ti wọn n pe fun Orilẹ-ede Yoruba lohun, nitori itanjẹ lasan ni wọn n ba kiri.

Wọn ni ninu gbigbe pọ ba a ṣe wa lati ọdun gbọọrọ ni alaafia wa, ẹnikan ki i da duro ko niyi bii ẹni to lero lẹyin rẹpẹtẹ.

To ba jẹ nipa ofin ti Naijiria n lo lọwọlọwọ yii, ẹgbẹ YAF ni awọn fara mọ ọn pe ki wọn ṣe agbẹyẹwo rẹ, ki wọn tun un ṣe, ki ohun to tọ si ẹya kọọkan le maa tẹ wọn lọwọ. Ṣugbọn nipa ti pinpin Naijiria, wọn ni kawọn agbofinro tete maa fọwọ ofin mu awọn alajangbila to n pe fun idasilẹ Yoruba, kawọn araalu to ba si ni wọn lẹgbẹẹ naa tete maa tu aṣiri wọn sita.

Leave a Reply