Awọn agbebọn ya wọ otẹẹli l’Ayetoro-Ekiti, wọn ji eeyan mẹta gbe, wọn tun fipa ba obinrin kan lo pọ

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Inu ibẹru-bojo lawọn eeyan ilu Ayetoro, nijọba ibilẹ Ido/Osin, nipinlẹ Ekiti, wa bayii, pẹlu bii awọn Fulani agbebọn kan ṣe sadeede ya wọ ileetura kan to wa niluu naa ti wọn n pe ni Diamond Hotel, ti wọn si gbe eeyan mẹta lọ.

Bakan naa ni wọn tun fipa ba ọdọmọbinrin kan to jẹ oṣiṣẹ ileetura naa lo pọ, ti wọn tun ṣe lara awọn oṣiṣẹ ibẹ leṣe ki wọn too ji wọn gbe lọ.

Ni nnkan bii aago mẹsan-an aabọ alẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, la gbọ pe awọn agbebọn naa ti ko din ni ọgbọn ya wọ ileetura yii pẹlu ibọn ati ohun ija oloro loriṣiiriṣii pẹlu ọkada, ti wọn si n yinbọn soke ki wọn too wọ inu ileetura naa lọ.

Ẹnikan to n gbe inu ilu naa to pe ara rẹ ni Peter Otiko ṣalaye pe oju ọna kan to lọ si ilu Ewu-Ekiti lawọn agbebọn yii gba. Oju ọna yii kan naa ni awọn agbebọn kan ti yinbọn mọ Ọba Adetutu Ajayi ninu oṣu kẹrin, ọdun yii.

Otiko ni ki wọn too wọnu ileetura naa lọ ni wọn ti kọkọ kọju ija si ọlọdẹ to n ṣọ ibẹ ti wọn porukọ rẹ ni Sunday. Niṣe ni wọn fi ada ṣa a lọwọ yannayanna ki wọn too wọ ileetura naa lọ.

O fi kun un pe lẹyin ti wọn raaye wọle ni wọn ko eeyan mẹta to wa nibẹ pẹlu ẹni kan ti orukọ rẹ n jẹ Idowu to jẹ oṣiṣẹ ileetura naa. Lẹyin eyi ni wọn mori le ọna to kọja lọ si ilu Ewu-Ekiti, ti wọn si n yinbọn soke lakọ lakọ bi wọn ṣe n lọ.

Iṣẹlẹ yii ti ko gbogbo ilu naa sinu wahala, wọn ko si ti i mọ ibi ti awọn mẹta ti wọn ji ko yii wa titi di asiko ta a pari iroyin yii.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, oludari  awọn Amọtẹkun  nipinlẹ Ekiti, Ajagun-fẹyinti Joe Kọmọlafe, sọ pe oun ko le sọ ni pato boya awọn Fulani lo ṣiṣẹ buruku naa. O fi kun un pe ni deede aago mẹwaa aabọ alẹ loun sadeede gba ipe kan pe iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, ti oun si ko awọn ọmọ ẹgbẹ oun lọ si ilu naa lọgan, ṣugbọn awọn agbebọn naa ti fi ilu silẹ ki awọn too de ibẹ.

Ọga Amọtẹkun yii sọ pe awọn ti bẹrẹ iwadii ati igbesẹ to daju lori iṣẹlẹ naa, ati pe wọn ti ko awọn to fara pa lọ sileewosan ijọba apapọ to wa niluu Ido-Ekiti, nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ.

 

 

 

 

Leave a Reply