Ileeṣẹ amunifọba ti wọn n pe ni DSS ti ṣalaye siwaju si i pe idi ti awọn fi n wa Oloye Sunday Adeyẹmọ ti gbogbo eeyan n pe ni Sunday Igboho ni pe o n mura ogun si Naijiria, o fẹẹ ba Naijira jagun, ati pe nitori ẹ lo ṣe n ko ọpọlọpo ibọn ati awon ohun ija oloro mi-in pa mọ.
Alukoro awọn DSS yii, Peter Afunaya, ṣalaye eyi mọ ọrọ nigba to n sọ idi ti awọn fi lọ si ile Sunday Igboho loru Ọjọbọ to kọja yii ni. O ni fara han pe ọkunrin naa ti mura lati doju ijọba bolẹ nipa awọn iwa janduku to n hu, ohun ti awọn si ṣe n fẹ ko wa sọ ti ẹnu rẹ niyi ati pe awọn ko ni i sinmi titi di igba ti awọn yoo fi ri i mu.
Ṣugbọn ohunti awọn amoye laarin ilu n sọ ni pe ko le jẹ nitori eyi ni won ṣe n wa a, nitori Igboho funra rẹ ti jade pe oun kọ loun ni awọn ohun ija ti wọn ba nile oun, oogun ibilẹ ibẹ nikan ni toun. Idi kan naa ti wọn fi le maa le e kiri ni lati fopin si iwọde to n ṣe nipa pe ki gbogbo ọmọ Yoruba gba ominira kuro ni Naijiria, ki wọn ni orilẹ-ede tiwọn. Eyi ni ko dun mọ ijọba orilẹ-ede yii ninu, ti awọn agbofinro naa si fi n wa kiri lati ṣe e leṣe, ati lati fi i pamọ fun igba pipẹ.
Awọn awoye yii tilẹ ni iwọde ti wọn fẹẹ ṣe lEkoo ni Satide oni yii wa lara ohun to jẹ ki awọn aja ijoba wọnyi mu iṣẹ naa ni kankankan bẹẹ, nitori wọn ko fẹ ki iwọde naa waye rara. Awọn ti wọn n da si ọrọ ni bi eeyan ba fi oju inu wo ariwo ti awọn ọlọpaa ati oloṣelu Eko ti n pa lati ọjọ mẹta yii lori pe ki Sunday Igboho ati awọn eeyan rẹ ma wa si Eko, ko ni ṣoro lati mọ pe ejo ọrọ naa lọwọ ninu.
Ṣugbọn awọn DSS ko sọ eyi o, wọn ni awọn n wa Igboho nitori pe o fẹẹ dalu ru ni.