Ọwọ tẹ Ibrahim to n ko nnkan ija ogun fawọn ẹgbẹ afẹmiṣofo ni Sango

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ọkan ninu awọn ẹgbẹ afẹmiṣofo ti wọn n pe ni ISWAP(The Islamic State-West Africa Province) ni ọkunrin kan, Ibrahim Musa, maa n ta awọn nnkan ija oloro fun gẹgẹ bawọn ṣọja ti wọn mu un loṣu to kọja yii ṣe wi.

Agbegbe Sango, nipinlẹ Ogun, ni wọn ni awọn ti mu Ibrahim lasiko to n lọ s’Ekoo ti yoo ti ko awọn nnkan ija to fẹẹ ta ọhun.

Wọn n dọdẹ agbegbe kiri bii iṣe wọn ni ikọ ologun ‘Operation Awatse’ yii ṣalabapade Musa Ibrahim. Ojule kọkanlelelọgbọn, Opopona Abartura, ni Sango, ni wọn ti mu un.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, wọn ni Ibrahim fẹẹ ba awọn ISWAP wa nnkan ija ogun rẹpẹte si i ni, eyi ti wọn n lo lati fi pa awọn eeyan, ti wọn si n daamu awọn alaiṣẹ ni Maiduguri, nibi to jẹ bi wọn ṣe n pa awọn alaiṣẹ ni wọn n dana sun ile, ti wọn si n le awọn mi-in kuro nile patapata.

Koda, a gbọ pe lẹyin ọjọ diẹ tawọn ikọ Boko Haram ati ISWAP  ṣepade lati pawọ-pọ maa daamu awọn ipinlẹ Oke-ọya ni Naijiria atawọn orilẹ-ede eeyan dudu mi-in ni wọn mu Ibrahim yii.

Bo tilẹ jẹ pe wọn kọ yọnda fọto Ibarahim Musa fawọn akọroyin, Adele ẹka to n ri si eto iroyin lọfiisi awọn ologun, Benard Onyeuko, fidi mimu ti wọn mu un yii mulẹ. O ni o wa nibi tawọn fi i pamọ si lati ṣalaye ara ẹ daadaa.

Onyeuko ni ki i ṣe Musa nikan lawọn mu, awọn tun mu ọkunrin kan to n ji epo wa, Oyeṣọla Saheed, lagbegbe Alimọṣọ, l’Ekoo.

O ni Oyeṣọla jẹwọ fawọn pe ẹnikan torukọ ẹ n jẹ Akanbi ni olori ikọ to n bẹ ọpa epo kiri lagbegbe naa, bawọn si ti mu afurasi yii lawọn fa a le ẹka to yẹ lọwọ pẹlu mọto atawọn irinṣẹ ti wọn fi n ji epo wa to n ko kiri.

 

Leave a Reply