Ẹyin awakọ, e yee rin ọna Idiroko lẹyin aago mẹfa irọlẹ o – FRSC

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

FRSC ẹka Idiroko, nipinlẹ Ogun, ti ṣekilọ fawọn awakọ to n gba oju ọna yii lati yee tirafu gba ibẹ lẹyin aago mẹfa irọlẹ. Wọn ni ewu gidi ni oju ọna Idiroko to ba ṣẹ n di aago meje alẹ lọ soke.

Ọga FRSC lẹkun Idiroko, Akinwunmi Ọlaluwọye, lo sọ eyi di mimọ l’Ọjọbọ to kọja yii, nigba to ṣalaye pe awọn onifayawọ  to n na oju ọna yii pọ. Bi wọn si ṣe maa n wa ọkọ le fa ijamba, ti ẹni ti ko ra nibẹ yoo san.

Yatọ si eyi, Ọlaluwọye la awọn awakọ lọyẹ pe bi wọn ba n gba ọna Idiroko lọwọ alẹ, bi ọkọ ba bajẹ sọna, o le di ohun ti awọn adigunjale yoo ka iru ọkọ bẹẹ mọ, ti wọn yoo si gba tọwọ awọn ti wọn ba wa nibẹ, tabi ki wọn pitu to ju bẹẹ lọ fun wọn.

Bakan naa lọga FRSC yii sọ pe bi ijamba ba ṣẹlẹ lọwọ alẹ, yoo ṣoro lati ri awọn oluranlọwọ ti yoo ṣaanu awọn ti ijamba naa kan. Bi mọto ba si bajẹ sọna lọwọ aajin, ta ni yoo ba wọn ṣe atunṣe rẹ, iṣoro ati idaamu nla ni awọn ero ọkọ bee yoo kan ko si.

Fun awọn idi wọnyi, o rọ awọn awakọ to n na agbegbe Idiroko yii, pe ti aago mẹfa irọlẹ ba ti lu, ki wọn duro sibi ti wọn ba wa, to ba di lọjọ keji ti ojumọ ba ti mọ daadaa, ki wọn mu irin ajo wọn pọn. Ọlaluwọye sọ pe eyi daa fun wọn ju ki wọn maa fẹmi wewu nitori ikanju lọ.

O lawọn ko ni i dawọ idanilẹkọọ duro fawọn awakọ jake-jado, ṣugbọn kawọn ọlọkọ naa maa ri i pe wọn n tẹle ofin irinna, ki wọn si maa ri i pe mọto wọn wa nipo to daa ki wọn too gbe e soju popo.

 

 

 

Leave a Reply