Ẹ fura o, Gumi fẹẹ fi abẹwo to ṣe siluu Igboho ko awọn Fulani darandaran wọlu ni o – Awọn ọmọ Oke-Ogun

Faith Adebọla 

Ẹgbẹ AOD, to n ri si idagbasoke agbegbe Oke-Ogun, (Alliance for Oke-Ogun Development) ti sin awọn eeyan ni gbẹrẹ ipakọ pe ki wọn fura gidigidi si abẹwo ojiji ti gbajugbaja aṣaaju ẹsin Islam, Sheikh Ahmad Abubakar Gumi, ṣe siluu Igboho, l’Ọjọruu, Wẹsidee yii, o ni abẹwo ọhun ki i ṣe fun iṣọkan gẹgẹ bi wọn ṣe n sọ, o ni ọkunrin naa fẹẹ gbọna ẹyin kogun ja’lu ni, wọn fẹẹ dọgbọn da awọn Fulani darandaran ti wọn ti le kuro lagbegbe naa pada ni.

Ọtunba Abiọdun Fasasi to jẹ Oluṣekokaari ẹgbẹ naa lapapọ lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade kan toun ati akọwe ẹgbẹ fi lede l’Ọjọbọ, Tọsidee, lori ọrọ yii. Wọn ni ṣaaju akoko yii lawọn ti gbọ nipa etekete tawọn kan n da ti wọn pe ni ‘Fulanization Agenda’ lede eleebo, lati dana wahala silẹ lakọtun lagbegbe Oke-Ogun, ati lati sọ agbegbe naa di tawọn Fulani darandaran.

Wọn sọ ninu atẹjade naa pe inu Gumi o dun si bawọn ṣọja ilẹ wa ṣe ṣina bolẹ fawọn janduku ajinigbe, awọn darandaran agbebọn ti wọn n han awọn ara Oke-Ọya leemọ lọwọlọwọ, o ni iṣẹlẹ yii lo mu ki wọn sare bẹrẹ igbesẹ abẹwo abaadi yii.

“Ọgbọn ni wọn n da o, wọn fẹẹ wa ibi ti wọn maa fidi awọn Fulani darandaran kalẹ si ni o,” bẹẹ ni wọn kegbajare ninu atẹjade ọhun.

Wọn tun ke sawọn ọba alaye lagbegbe Oke-Ogun lati wa lojufo, wọn ni oju lalakan fi n sọ’ri, ki wọn ma sun asunpiye lori ọrọ yii, ki wọn maa ṣakiyesi awọn agbẹyinbọbọjẹ ati awọn to ba fẹẹ gbabọde fun ilẹ Yoruba, ki wọn si tete taṣiiri wọn faye gbọ.

Bakan naa ni wọn rọ ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ilẹ wa, DSS, lati pe Gumi atawọn ẹmẹwa ẹ, ki wọn si fọrọ wa wọn lẹnu wo lori abẹwo ojiji ti wọn lawọn n ṣe kiri ilẹ Yoruba ọhun.

Bi ẹgbẹ AOD ṣe n sọ tiwọn, bẹẹ ni akorijọ awọn ẹgbẹ to n ja fun ominira ilẹ Yoruba, (Coalition of Yoruba Self-Determination Groups) sọ pe abẹwo Sheik Ahmad Abubakar Gumi si ilu Igboho, nipinlẹ Ọyọ, yii mu ifura lọwọ gidi, wọn ni alami lawọn alejo yii waa ṣe. Atẹjade kan ti ẹgbẹ naa fi lede, eyi ti Akọwe agba, Dokita Steve Abioye, buwọ lu sọ pe ajẹnda bonkẹlẹ kan wa nidii abẹwo ọhun, awọn o si le maa woran wọn bẹẹ.

Wọn ni “Ọlọgbọn-kọgbọn ati eletekete lawọn ẹya Fulani, bẹẹ naa si ni Gumi ṣe n huwa yii, o jọ pe wọn fẹẹ dọgbọn fa awọn eeyan mọra ki wọn le ribi wọle si wọn lara ni, paapaa bi wọn ṣe n ri i pe iṣejọba Aarẹ Mohammadu Buhari ti n kogba sile, ọpọlọ wọn n wa ibi to tutu to maa ba si ni.

Ki lo de ti Gumi o lọ sawọn ilu ati ileto ilẹ Yoruba mi-in, to jẹ Igboho, l’Oke-Ogun, ilu abinibi Oloye Sunday Igboho ni wọn yan laayo. Ta lo pe wọn, ta si ni wọn waa ba?”

Ẹgbẹ naa ni kawọn ọmọ Yoruba ṣọra, ki wọn ma lọọ lu pampẹ ọran tawọn alejo ojiji yii fẹẹ kẹ fun iran Yoruba.

Ṣe laipẹ yii, ninu fidio kan ti ileeṣẹ agberoyinjade lori ayelujara kan, Oodua Heritage, gbe sori afẹfẹ, Sheikh Gumi ati Ọga agba Ajọ abanigbofo eto ilera apapọ (National Health Insurance Scheme) Ọjọgbọn Usman Yusuf, lo ṣaaju ikọ awọn alejo kan ti wọn ṣabẹwo siluu Igboho, ilu abinibi ajijangbara ilẹ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho, Gumi lawọn n lọ kaakiri lati fihan pe ko si ohunkohun to maa pin Naijiria yii, gbogbo wa gbọdọ maa wa papọ titi aye ni, bẹẹ lawọn eeyan ya fọto ati fidio nitosi ileewe Muslim Grammar School, Modeke, Igboho, nipinlẹ Ọyọ.

Ninu ọrọ to sọ, Gumi ni, “Ilu Igboho la wa yii, a ṣabẹwo siluu yii lonii. A mọ pe ilu tawọn ẹlẹsin Musulumi pọ si ni, a si tun ri awọn maaluu ti wọn jẹko ninu Kara wọn nibi. Eyi lo maa jẹ kawọn eeyan mọ pe awa ọmọ Naijiria gbọdọ jọ maa gbe pọ ni, tori emi o ri nnkan kan nibi yii to le mu kawọn kn maa pariwo ipinya, tabi pe ki wọn lawọn o ṣe Naijiria mọ.”
Bakan naa ni Ọjọgbọn Usman Yusuf naa sọrọ, o ni: “Ilu Igboho ree o, ilu tawọn eeyan mọ mọ ọkunrin to wa lahaamọ lorileede Bẹnẹ yẹn, ọkan naa ni wa ni Naijiria, ọkan naa la o si maa jẹ titi aye.
A ti lọ kaakiri, a si ri apẹẹrẹ bo ṣe yẹ kawọn eeyan maa gbe papọ. Tori ẹ naa la ṣe wa sibi, lati fihan pe a le jọ laṣepọ, lai ka iru ẹsin yoowu ti a n ṣe si.

Nigba ta a lọ siluu Ileṣa (ipinlẹ Ọṣun), a ri i bawọn eeyan ṣe n gbe papọ, atawọn ẹlẹsin Kristẹni ati Musulumi, ati Yoruba ati Hausa. Bẹẹ naa la ṣe ri i niluu Igboho yii, eyi to fihan pe awọn ọtọọkulu aarin wa ni wọn fẹẹ pin wa niya, awọn araalu o niṣoro kankan.
Tori naa, a wa sibi pẹlu iṣọkan Naijiria ni, iṣọkan naa la o si maa wa titi aye.”

Leave a Reply