Ọmọ ọdun mọkanla ti ọkọ anti ẹ fipa ba lo pọ ti bimọ ọkunrin

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

 Ọmọ ọdọ ati oluranlọwọ ni wọn tori ẹ mu ọmọdebinrin yii fun anti ẹ pe ko maa gbe lọdọ obinrin naa, ko si maa ran an lọwọ. Ṣugbọn ọkọ anti ọhun fipa ba ọmọdebinrin tọjọ ori ẹ ko ju mọkanla lọ naa lo pọ titi, o si loyun. Oyun ọhun lo ti fi bimọ ọkunrin bayii.

Ipinlẹ Benue niṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ, gẹgẹ bi ẹka iroyin Punch to ro o ti wi. Iṣẹ ọlọdẹ to n ṣọ ẹnu ọna ni ọkọ anti rẹ yii n ṣe ni Yunifasiti ipinlẹ Benue, ṣugbọn niṣe lo sọ ọmọ kekere naa di nnkan ibasun lọpọ igba, wọn lo fipa ba a lo pọ gidi titi tọmọ fi loyun mọ ọn lọwọ ni.

Ajafẹtọọ ọmọniyan torukọ ẹ n jẹ  Andrew Obeya lo ti n fi bo ṣe n lọ lori ọmọ yii han saye tipẹ. Oun lo maa n gbe e sori ayelujara ni gbogbo asiko to fi wa ninu oyun naa.

Lopin ọsẹ yii lo si gbe e jade pe ọmọ ọdun mọkanla naa ti bimọ ọkunrin o, ati pe oun atọmọ rẹ naa wa lalaafia lọsibitu, wọn n ṣe daadaa.

Ọjọ Jimọ ti i ṣe ọjọ kẹrinla, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022 yii, lọmọ naa sọkalẹ layọ gẹgẹ bo ṣe wi.

Ibeere kan tawọn eeyan n beere bayii ko ju pe ṣe ọkọ anti rẹ to fun un loyun ti wa lẹwọn ṣa? Wọn ni iru rẹ ko yẹ lawujọ eeyan oun o.

Leave a Reply