Awọn ọmọ Naijiria to n kawe ni Ukraine pariwo: Ijọba Buhari, ẹ waa ko wa wale o

Faith Adebọla

Latari akọlu ati ija gbigbona to n lọ lọwọ lorileede Ukraine, ọgọọrọ awọn ọmọ Naijiria, paapaa, awọn to n kawe lọwọ lawọn ileewe giga lorileede naa ti kegbajare sijọba apapọ pe awọn ti ha sorileede naa, wọn ni kijọba waa ran awọn lọwọ, ki wọn si ṣeto lati doola ẹmi awọn.

Awọn obi awọn ọmọ naa tun parọwa si Aarẹ Muhammadu Buhari pe ki wọn tete ṣeto lati lọọ ko awọn akẹkọọ wọnyi kuro niluu Ukraine, wọn ni diẹ lara wọn ti raaye ja ajabọ si orileede Poland, ṣugbọn ọpọ lara awọn ọmọ Naijiria ni ija to n lọwọ naa ti ka mọ ilẹ Ukraine, bo tilẹ jẹ pe awọn kan lara wọn raaye fẹsẹ rin irin wakati mẹwaa kọja si ẹnubode Poland, wọn lawọn aṣobode naa yọnda fun wọn lati kọja, ti wọn ba ri kaadi idanimọ akẹkọọ lọwọ wọn, tabi iwe abanigbofo wọn, atawọn nnkan idanimọ mi-in.

A gbọ pe nnkan bii ẹgbẹrun mẹrin (4,000) lawọn ọmọ ilẹ wa to n kawe lọwọ lorileede Ukraine, ileeṣẹ Aarẹ si ti gba wọn lamọran lati wa ibi fori pamọ si na titi ti eto yoo fi pari lati ko wọn kuro lọwọ ewu.

Ṣugbọn aṣoju orileede Ukraine ni Naijiria, Kidoda Valerii, ti sọ pe ko ti i si anfaani lati ko awọn eeyan ti ogun ka mọ ọhun lọwọ yii, o ni gbogbo ileeṣẹ ọkọ ofurufu ati papakọ ofurufu ilẹ Ukraine nijọba ti ti pa. Valerii sọrọ yii di mimọ nigba ti minisita fun ọrọ ilẹ okeere lọọ ṣabẹwo si i lọfiisi rẹ niluu Abuja, lati ṣeto bi wọn ṣe maa daabo bo awọn ẹni ogun ka mọ ọhun.

Leave a Reply