Ọwọ awọn ṣọja tun tẹ afurasi meji mi-in ti wọn lọwọ ninu ikọlu Ọwọ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọwọ ologun orile-ede yii ti tun tẹ awọn afurasi meji mi-in lori ikọlu awọn agbebọn to waye ninu ṣọọsi Katoliiki Francis Mimọ, to wa niluu Ọwọ, lọjọ karun-un, oṣu Kẹfa, ọdun ta a wa yii.

Mẹjọ Jẹnẹra Jimmy Akporto to jẹ adari ẹka iroyin awọn ọmọ ologun lo sọrọ yii ninu atejade kan to fi sita laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.

Awọn afurasi mejeeji ọhun lo ni ọwọ awọn ṣọja at’awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ tẹ ni Omialafara (Omulafa), nijọba ibilẹ Ọsẹ, nipinlẹ Ondo, lẹyin wakati diẹ ti ileeṣẹ ologun ti kọkọ kede pe awọn ti fi pampẹ ofin gbe marun-un lara awọn ọdaran to lọwọ ninu akọlu naa.

Akpor ni ọkan ninu awọn ọdaran tọwọ awọn ṣẹṣẹ tẹ ọhun, ẹni t’orukọ rẹ n jẹ Abdulhaleem, pẹlu awọn adari ẹgbẹ agbesunmọmi ISWAP lo ni wọn ti kọkọ ṣe ikọlu si ojuko awọn ologun to wa ni Okene, nijọba ibilẹ Okene, nipinlẹ Kogi, ninu eyi t’ọpọ awọn eeyan ku si.

Awọn onisẹẹbi ibi naa lo ni ọwọ palaba wọn pada ṣegi nipasẹ akitiyan awọn ologun atawọn ọtẹlẹmuyẹ to wa lagbegbe Eika, nijọba ibilẹ Okehi, nipinlẹ Kogi, lọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹjọ, ọdun 2022.

Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, ti kọkọ fi atẹjade kan sita l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ninu eyi to ti sọ fawọn eeyan pe, aṣiṣe lawọn ologun kọkọ ṣe pẹlu bi wọn ṣe kede orukọ afurasi kan ti wọn n pe ni Idris Ojo pẹlu awọn afurasi marun-un ti wọn kọkọ mu lori ikọlu Ọwọ.

O ni Idris wa lara awọn ẹlẹwọn ti wọn sa kuro lọgba atunṣe Kuje, laipẹ yii, to si waa sapamọ si ọdọ ẹgbọn rẹ kan l’Akurẹ nibi tọwọ ti pada tẹ ẹ. Aketi ni boya bi wọn ṣe ti ọkunrin naa mọ inu ahamọ kan naa pẹlu awọn afurasi agbebọn tọwọ tẹ lori ikọlu inu ṣọọsi Katoliiki Francis Mimọ, ilu Ọwọ, lo jẹ kawọn ologun ṣeeṣi ka orukọ rẹ mọ wọn.

 

Leave a Reply