Nitori ẹsun janduku, wọn wọ ọba alaye lọ si ile-ẹjọ ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni wọn wọ ọba tilu Samora, nijọba ibilẹ Irẹpọdun, nipinlẹ Kwara, Ọba Matthew Idowu Ajiboye, lọ siwaju ile-ẹjọ Magistreeti kan niluu Ilọrin, fẹsun pe o ko awọn janduku sodi, ti wọn si lọọ kọ lu Ọba Ọlọba tilu Eju, Alaaji Maroof Afọlayan Adebayọ, ti wọn dijọ wa ni ijọba ibilẹ kan naa ni aafin rẹ. Iroyin lati ọwọ awọn ọlọpaa sọ pe Ọba Ajiboye, pẹlu awọn eeyan marun-un miiran, Tijani Musibau, Kuburat Sọdiku, Afọlayan Sukiru, Usman Raufu, Tunde Arinwoye ati Saheed Bello, ti ọwọ ti tẹ ni wọn lọọ ṣe akọlu si Ọba Ọlọba ati mọlẹbi rẹ laafin pẹlu ohun ija oloro, ti ọpọ si fara pa yannayanna nibi iṣẹlẹ ọhun. Wọn ni wọn tun ji awọn ohun eelo ko lọ, to fi mọ owo ilẹ yii ati t’Oke-okun ko lọ laafin. Agbefọba, Ojo Oluwaseun, sọ fun Ile-ẹjọ pe iwadii si n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa, to si rọ adajọ ko sun igbẹjọ naa siwaju. Onidaajọ Abdullahi Badmus, gba beeli ọba alaye naa pẹlu ẹgbẹrun lọna ẹdẹgbẹta Naira (N500,000) pẹlu ẹlẹrii meji, ti wọn yoo san iye owo yii ba kan naa, wọn si gbọdọ maa gbe ni agbegbe ile-ẹjọ. Lẹyin eyi lo sun igbẹjọ si ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2022.

Leave a Reply