Ọlaiya dọbalẹ, o yi gbiiri, nigba ti MC Oluọmọ fun un ni kọkọrọ mọto tuntun

Jọkẹ Amọri

Bii ala ni ọrọ naa ri loju gbajugbaja elere ori-itage nni, Oloye Ẹbun Ọlaiya, ẹni ti gbogbo aye mọ si Ọlaiya Igwe, nigba ti ọga awọn onimọto Eko pata, Alaaji Musiliu Akinsanya, MC Oluọmọ, fun un ni kọkọrọ mọto tuntun. Lọwọ alẹ ni ọrọ naa ṣẹlẹ, ṣugbọn bi ilẹ ti ṣu to naa, gbalaja ni Ọlaiya dọbalẹ, to si n pariwo ‘Olu-Ọmọ!’, ‘Olu-ọmọ, bẹẹ lo n yi gbirigidi nilẹ!’

Ninu fidio kekere to jade nibi iṣẹle naa, MC Oluọmọ ati Ọlaiya Igwe lo n rin lọ, o si han pe alẹ ti lẹ, bi wọn ti n rin lọ ni wọn n takurọsọ. Lẹẹkan naa ni wọn de ibi mọto jiipu kan, MC Oluọmọ si tẹsẹ duro diẹ, n lo ba yọ kọkọrọ, lo ju u le Ọlaiya lọwọ, to si sọ fun un pe mọto rẹ niyẹn. Ọkunrin onitiata naa duro sii, lẹyin naa lo pariwo ‘Ooooroo!’

Nibi ti iyanu ti mu ọkunrin yii ni MC Oluọmọ ti bẹre si i rin lọ ni tiẹ, o si ti rin siwaju diẹ ki Ọlaiya too sare ji loju oorun to ro pe oun wa. Bo ti ta giri to ri i pe ootọ ni kinni naa, niṣe lo ki ere mọlẹ, to si le Olu-ọmọ ba. Bo ti ba a lo digbolulẹ, to si bẹrẹ si i yi gbiiri nilẹ, nitori kinni naa ya a lẹnu pupọ. Bo ti n yi gbiiri ni MC n rọ ọ ko ma ṣe ara rẹ leṣe.

O ṣee ṣe ko jẹ ohun to mu ọrọ naa ya Ọlaiya lẹnu, to si mu inu rẹ dun ju ni asiko ti kinni naa bọ si. Laipẹ yii ni ọkan ninu awọn ololufẹ Ọlaiya to wa ni Amẹrika ba a ja lori atilẹyin ti oun ati awọn elere ẹgbẹ rẹ lọọ ṣe fun Aṣiwaju Bọla Tinubu, ti wọn si gbe fidio jade, ti wọn kọrin daadaa ki ọga awọn oloṣelu naa, ti wọn si ni oun ni ki gbogbo aye tẹle, nitori oun nikan lo le ṣe e. Ọrọ naa lo bi ololufẹ Ọlaiya yii ninu, to si pe e sori foonu lati Amẹrika.

Ọrọ naa dija laarin awọn mejeeji, nitori bo ti n sọrọ ni Igwe naa n da a lohun, ọrọ buruku ti wọn si sọ si ara wọn ko ṣee ka tan. Ṣugbọn ọkan wa ninu rẹ to dun Ọlaiya, iyẹn nigba ti ọkunrin naa sọ fun un pe pẹlu gbogbo kurukẹrẹ to ti n ṣe lẹyin Tinubu ati awọn mi-in, ṣebi pẹnkẹlẹmẹẹsi mọto to n gun kiri niyẹn. O ni mọto naa ko yatọ si posi-to-n-rin-ni-titi, o ni apẹẹre pe iya gidi n jẹ ọkunrin agba oṣere naa ni. Igwe gbiyanju lati sọ le ọro naa, sugbọn awawi lasan lo n wi. Fidio naa si jẹ eyi to kari aye.

O ṣee ṣe ko jẹ eyi ni ohun ti MC Oluọmọ ri, to si mura lati ṣeranlọwọ mọto tuntun fun Igwe. Ọlaiya funra rẹ ki i wọn nile ati ni ayika Oluọmọ, aipẹ yii lo wa nibẹ nigba ti ọmọde olorin ti wọn n pe ni Portable lọọ ki Oluọmọ, Ọlaiya lo si da bii Baa-meto ọjo naa, to n sọ ohun ti Portable yoo ṣe to ba fẹẹ jẹ ọmoloju Olu-ọmọ.

Akọkọ kọ niyi ti MC Oluomo yoo ran awọn oṣere lọwọ, eyi lo si mu ko jẹ gbogbo awọn oṣere yii ni wọn maa n rin sun mọ ọn, ti wọn si maa n sọrọ rẹ daadaa. Lati igba ti ọrọ ibo ti wa n sun mọ bayii, ti Tinubu si ti jade, gbogbo ara pata ni MC Oluọmọ fi n ṣe atilẹyin to ba le ṣe lori ọrọ yii, ohun to si jẹ ki Igwe jẹ ninu anfaani ohun to n lọ naa niyi o. Awọn ololufẹ Ọlaiya Igwe ti bẹrẹ si i ki i ku oriire, ti wọn si n ṣadura fun un pe mọto naa ko ni i fori sọpẹ, ko ni i fori sọgi!

Leave a Reply