Nitori owo, Kamalideen gun alaamojuto ibi ti wọn ti n ta tẹtẹ pa ni Badagry

Monisọla Saka

Ọkunrin ẹni ọdun marundinlogoji (35) kan, Kamalideen Raji, lọwọ awọn agbofinro ti tẹ fun ẹsun pe o gun alakooso ileeṣẹ ti wọn ti n ta tẹtẹ lọtiiri (lottery) pa lagbegbe Badagry, nipinlẹ Eko, nitori gbese.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundenyin, lo fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ninu atẹjade to fi lede lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

Hundenyin ṣalaye pe afurasi yii pa alamoojuto ṣọọbu ti wọn ti n ta tẹtẹ. Nitori aigbọra-ẹni-ye yii lawọn agbofinro ẹka Area K, ti gbe e, to si ti wa lakolo wọn.

Nigba to n sọrọ, o ni, “Afurasi ọhun ti wọn fi panpẹ ofin gbe ni nnkan bii aago mọkanla aarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ keji, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, lo gun ọkunrin alamoojuto ibudo lọtiri kan lẹẹmeji nibi ọrun rẹ nitori ede-aiyede to waye laarin wọn latari gbese.

“Wọn gbiyanju lati du ẹmi arakunrin naa pẹlu bi wọn ṣe gbe e digbadigba lọ sileewosan ijọba ilu Badagry, ṣugbọn to pada gbẹmii mi”.

O fi kun un pe, Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Abiọdun Alabi, ti paṣẹ pe ki wọn taari ẹjọ naa lọ si ẹka to n ri si iwadii iwa ọdaran, CID, to wa ni Panti, nipinlẹ naa, fun iwadii to peye.

Leave a Reply