Ọlawale Ajao, Ibadan
O kere tan, ẹni mẹrin ni wọn yinbọn pa, bẹẹ ni wọn ji ọpọ eeyan gbe, nigba ti wọn ji aimọye eeyan gbe lasiko tawọn agbebọn ṣoro fawọn agbẹ atawọn arinrin-ajo ninu ikọlu meji ọtọọtọ n’Ibadan, lọsẹ to kọja.
Abule Fẹkọ, nitosi Dominion University, lọna Eko s’Ibadan, lọkan ninu awọn iṣẹlẹ yii ti waye, nigba ti awọn agbebọn gẹgun sinu igbo lẹgbẹẹ ọna naa lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja, iyẹn lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022 yii, ti wọn bẹrẹ si i yinbọn mọ awọn ọkọ to n ti Eko lọ s’Ibadan.
Ọkunrin ẹni ogoji (40) ọdun kan, Ọgbẹni Fatunmbi, wa lara awọn to fara gbọta ibọn ọhun, to si jẹ Ọlọrun nipe, ọlọpaa meji paapaa fara gbọta ibọn ninu awọn ikọlu naa, ọkan ku, ekeji si fara pa yannayanna.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, iyawo pẹlu awọn ọmọ meji ni Fatunmbi gbe sinu ọkọ Jiipu rẹ dudu kan bayii ti wọn n pe ni Toyota Rav4 ti wọn jọ n rinrin-ajo wọn jẹẹjẹ ki wọn too ko sọwọ awọn ajinigbe yii.
Oun nikan ni wọn yinbọn mọ ki wọn le ribi ji wọn gbe. Bo si tilẹ jẹ pe ibọn ba a, sibẹ, ko duro, o n rọju wa mọto lọ ṣaa ni ki ọwọ awọn ajinigbe ma baa to wọn.
Ẹjẹ to ti jade lara ọkunrin arinrin-ajo naa laarin asiko yii ti pọ ju, nigba to ṣe, ko ni okun kankan ninu mọ, lẹẹkan naa lọkọ gbokiti sinu igbo, nigba naa lọkunrin naa mi kanlẹ, to si dagbere faye.
Awọn oṣiṣẹ alaabo oju popo, iyẹn Federal Road Service Corps (FRSC), ni wọn gbe oku ọkunrin naa lọ si yara ti wọn n tọju oku si nileewosan ijoba ipinlẹ Ogun to wa niluu Iṣara-Rẹmọ, nipinle Ogun.
Ni nnkan bii aago mẹrin aabọ ọjọ keji iṣẹlẹ yii, ti i ṣe ọjọ Abamẹta, Satide to kọja, lawọn agbofinro ṣẹṣẹ ri oku ọkan ninu awọn ti wọn yinbọn pa wọnyi ninu igbo, nibi ti wọn ti n wa awọn ajinigbe ọhun kiri pẹlu awọn eeyan ti wọn mu nigbekun.
Wọn ko ti i ri oku awọn yooku titi di ba a ṣe n kọroyin yii, ṣugbọn awọn ajinigbe ti kan si mọlẹbi awọn ti wọn ji gbe, pe ki wọn tete gbe owo nla waa fun awọn ki awọn le yọnda ẹni wọn to wa ninu igbekun awọn.
Lara awọn arinrin-ajo ti awọn ẹruuku naa ji gbe l’Ọgbẹni Adigun Agbaje, ọkunrin onimọ iwe kan n’Ibadan.
ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii wakati meji ṣaaju iṣẹlẹ yii lawọn ọbayejẹ eeyan yii ti kọkọ pitu lagbegbe naa, labule kan ti wọn n pe ni Aba Agbo. Abule yii ko jinna si ilu Ogunmakin, nitosi Ibadan, bo tilẹ jẹ pe wọn ko raaye ṣiṣẹ ibi kankan nibẹ, nitori ti awọn ọlọpaa tete doju ija kọ wọn.
Lẹyin naa ni wọn ṣẹṣẹ lọọ gẹgun soju ọna Eko s’Ibadan, nibi ti wọn ti yinbọn pa eeyan bii meloo kan, ti wọn ṣe aimọye leṣe, ko too di pe wọn ji awọn kan gbe lọ sinu igbo rere, ti wọn si n beere ọpọlọpọ miliọnu Naira lọwọ awọn ẹbi wọn gẹgẹ bii owo irapada ẹmi wọn ki awọn ma baa yinbọn pa wọn.
Lọsẹ mẹta sẹyin la gbọ pe awọn kanranjagbọn ẹda wọnyi ti kọkọ ya wọ inu oko nla kan tibọntibọn labule kan ti wọn n pe ni Aba Agbo, nitosi Ibadan, ọkunrin ara ilẹ okeere kan to ni oko nla ọhun ni wọn fẹẹ ji gbe, ṣugbọn awọn ikọ eleto aabo ilu ta a mọ si sifu difẹnsi, sọ ipinnu naa di otubantẹ mọ wọn lọwọ pẹlu bi awọn agbofinro naa ṣe gbena woju wọn, koda wọn yinbọn pa ọkan ninu awọn ọbayejẹ eeyan naa nibi ti wọn ti jọ n fija pẹẹta.
Ẹni to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ f’ALAROYE ṣalaye pe “nigba ti wọn pada lọ sinu oko yẹn lọjọ Furaidee, meje ni wọn, aṣọ ṣọja lawọn kan ninu wọn wọ, gbogbo wọn ni wọn si gbe ibọn AK47 lọwọ.
Awọn to n ṣiṣẹ ninu oko yẹn ko mọ pe wọn ti fara pamọ sinu igbo to kọju si oko awọn. Ni nnkan bii aago mọkanla aarọ si aago mejila ọsan lawọn marun-un ninu wọn ya wọ inu oko yẹn.
“Wọn ti sun mọ ẹnu ọna abawọle ki baba to n ṣọ geeti too ri wọn. Nibi to ti n sare ti geeti lọwọ lọkan ninu awọn ajinigbe yẹn ti fipa taari ilẹkun mọ ọn laya, wọn si kọri taara sọna ọdọ alamoojuto oko yẹn ta a mọ si Manija.
“Manija bẹrẹ si i sa lọ nitori oun naa ti ri wọn lọọọkan, bẹẹ lawọn naa n fibọn dẹruba a pe niṣe lawọn yoo yinbọn pa a bi ko ba tete duro. Ṣugbọn Ọlọrun ba manija ṣe e, wọn ko ri i mu titi to fi ba inu oko koko kan to wa lẹgbẹẹ oko rẹ sa lọ mọ wọn lọwọ.
“Manija padanu foonu rẹ mẹtẹẹta nibi to ti n sa asala fun ẹmi ẹ. O jọ pe bo ṣe da awọn foonu naa silẹ lawọn ajinigbe ti ko wọn, ṣugbọn ko bikita, ṣe bi iku ba fẹẹ pa ni, to ba ṣi ni ni fila, ka maa tun dupẹ ni”.
Gẹgẹ bii iwadii akọroyin wa, awọn ọlọpaa to n paraaro oju titi kiri fun eto aabo lagbegbe naa ni wọn ko jẹ ki awọn agbebọn naa ri iṣẹ laabi kankan ṣe ninu oko ọhun lọjọ naa. Ibọn ti awọn ajinigbe yii n yin nigba ti wọn n le Manija lọ lawọn agbofinro ọhun gbọ ti wọn fi sare lọ sibẹ lati pese aabo.
Wọn fija pẹẹta pẹlu awọn ọbayejẹ ẹda naa. Amọ ṣaa, wọn yinbọn pa ọkan ninu awọn ọlọpaa naa, ọkan mi-in si ṣeṣe lapa ati ẹsẹ to bẹẹ to jẹ pe ileewosan lo gba a nitẹẹ ni kete ti ori ko yọ lọwọ wọn.
Ko ju wakati mẹta lọ lẹyin ti awọn ọlọpaa ko jẹ ki wọn ri eeyan gbe ninu oko abule Aba Agbo yii, lawọn kọlọransi eeyan yii tun lọọ binu gẹgun si ẹba ọna l’Abule Fẹkọ, nitosi Dominion University, lọna Eko s’Ibadan.
Ibi ti wọn ti ṣọṣẹ yii ko ju irin iṣẹju mẹẹẹdọgbọn (25) lọ si inu oko ti wọn ti kọkọ lọ ti awọn ọlọpaa ti le wọn ni nnkan bii wakati mẹta ṣaaju.
Bi wọn ṣe n yinbọn nidaamu n ba awọn awakọ to n ti Eko lọ s’Ibadan, ti awọn ọkọ si n kọ lu ara wọn nibi ti wọn ti n duro lojiji. Nibẹ lọpọlọpọ ero ọkọ si ti fara pa, ti ẹlomi-in paapaa ti ku sara lai tiẹ ti i foju kan awọn ẹruuku to n lepa wọn.
Lẹyin ti ẹni to ku, ti ku, ti awọn to fara pa, ti fara pa, lawọn ọdaju eeyan naa ko iwọnba awọn ti ko fara pa ninu awọn arinrin-ajo naa wọ inu igbo lọ.
ALAROYE gbọ pe fotofoto lawọn ẹrujẹjẹ ọdaran yii fi ibọn lu awọn ọkọ ti wọn da lọna naa. Diẹ ninu awọn ọkọ ọhun, ni ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Sienna kan, Hundai kan, mẹsidiisi kan pẹlu ọkọ bọọsi akero kan.
Ọkan ninu awọn awakọ ero to kagbako iku ojiji latari ikọlu naa ni wọn pe ni Sherif, ẹgbẹ ati apa osi ibọn awọn araabi ti ba a.
Ọkunrin ti wọn pe ni Sherif yii ti kọkọ n gbe ọgbẹ ibọn naa sa lọ, ṣugbọn oun naa ko rin jinna pupọ to fi ṣubu lulẹ to fi dagbere faye.
O wa lara awọn oku eeyan meji ti awọn agbofinro ri ninu igbo lọjọ Satide.
Nibi ti nnkan de duro bayii, awọn ọlọpaa pẹlu atilẹyin awọn agbofinro bii ṣọja, Amọtẹkun atawọn ọdẹ ibilẹ, labẹ akoso Oloye Sunday Ẹgẹ, ti i ṣe Oluọdẹ ilẹ Ibadan ti wa ninu aginju igbo bayii, nibi ti wọn ti n wa awọn ajinigbe naa kiri.