Inu baagi ti baba olowo yii n gbe lọ si Inidia lo ko oogun oloro rẹpẹtẹ si

Jọkẹ Amọri

Orileede India ni ọkunrin kan ti gbogbo eeyan mọ si baba olowo laduugbo wọn, nitori pe igbe aye ẹni to ri jajẹ to maa n gbe, Kingsley Celestino, dagbere fawọn mọlẹbi rẹ pe oun n lọ lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹta, yii. Ṣugbọn awọn mọlẹbi rẹ ko mọ pe ọkunrin naa ti ko ẹru ofin sabẹ baagi to di aṣọ atawọn nnkan mi-i to n ko lọ sirinajo yii si. Kingsley ti pese aaye kan si abẹ baagi to n gbe rinirin-ajo naa. Oogun oloro tijọba ilẹ Naijiria ti fofin de, Heroin, ti iwọn rẹ din diẹ ni kilo mẹwaa lo to sinu baagi mejeeji bẹbẹẹbẹ, lo ba ko aṣọ le wọn lori, o gba papakọ ofurufu ilẹ wa to wa niluu Ikẹja lọ, o n lọọ wọ baaluu, o fẹẹ gbe oogun oloro naa sọda si India.

Ṣugbọn ọwọ tẹ ọkunrin naa, ko le de orileede India to loun n lọ, bẹẹ ni ko le pada sile lọdọ awọn mọlẹbi rẹ, akata ajọ to n gbogun ti gbigbe ati lilo oogun oloro nilẹ wa, NDLEA, lo wa bayii to ti n ṣalaye bi oogun oloro ṣe de inu baagi rẹ.

Alukoro ajọ NDLEA, Fẹmi Babafẹmi, ṣalaye ninu atẹjade kan to tẹ ALAROYE lọwọ pe ọkọ ofurufu Qatar ni Kingsley, ẹni ọdun  mọkandinlaaadọta wọ, aaye awọn olowo ti wọn n pe ni business class lo gba to fẹẹ jokoo si. Ṣugbọn lẹnu ọna to fẹẹ gba lọ sibi ti yoo ti wọ baaluu lọwọ awọn NDLEA ti tẹ ọkunrin to wa lati ijọba ibilẹ Nnewi, nipinlẹ Anambra ọhun, ni wọn ba ko ma mu gaari si i lọwọ.

Nigba ti wọn n fi ibeere po o nifun pọ lo jẹwọ pe oniṣowo aṣọ ni oun, orileede India loun si ti maa n lọọ ra awọn aṣọ naa lati waa ta a ni Naijiria. Nigba to n dahun si ibeere pasipọọtu orileede Guinea to fi n rin irinajo naa, o ni ọmọ orileede naa ni iya to bi oun, Guinea Bissau loun si ti gba pasipọọtu ọhun.

Alukoro ajọ NDLEA ni iwadii awọn fi han pe aaye awon olowo, iyẹn buusiness class ni Kingsley to maa n rinrin-ajo ni gbogbo igba yii maa n jokoo si.

Leave a Reply